Líla Ìgbà Ìṣòro KọjáÀpẹrẹ
Ìdí tí A fi Ní ìrírí Àwọn Ìdánwò
Nígbàtí ó bá dé àkókò àwọn Ìdánwò nínú ìgbésí ayé wa, ọ̀rọ̀ kan tí ó máa ń wá sí wa ni ẹnu ni kílódé.Nítorí pé àdánwò le, ó máa ń dunni, ó sì máa ń bani nínú jẹ́, a sábà máa ń béèrè pé, “Kí nìdí tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí mi?” àti pé a kò fẹ́rẹ̀ ní ìdáhùn tí à ń wá. Wọ́n ń mú ká ṣiyèméjì nípa ohun tá a gbà gbọ́ torí pé a ń dán àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa wò.
Gẹ́gẹ́ bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Kínní, Jésù kọ́ wa pé a máa ní ìṣòro. Ìgbésí ayé gẹ́gẹ́bí ọmọ-ehin Krístì kò ní ṣa láì ní ìṣòro. Ilé ayé tí a wà ti wó ó sì dàrú pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó ti wó àti pé wọ́n ti dàrú tí wọ́n sì ṣe àwọn nǹkan tí ó ti bàjé tí ó si dàrú. Dájúdájú, awọn Ìdánwò yóò wà. Àwọn ènìyàn yóò ṣe àwọn ohun tí yóò pawá lára.A yóò ṣe àwọn ohun tí yóò pa àwọn ẹlòmíràn ati àwa fúnra wa lára. A le sé ní ìgbà àìmọ́, ṣùgbọ́n àwọn ìṣe wa le fa ìrora nínú ìgbésí ayé ẹlòmíràn. Bóyá pàápàá tiwa náà.
Èyí ni àwọn ìdí diẹ tí a fí la àwọn Ìdánwò kọjá:
Ìdàgbàsókè Nínú Ẹ̀mí
Láìka bí àdánwò ṣe wọnú ìgbésí ayé wa, a lè lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ láti fún ìwà àti ìgbàgbọ́ wa lókun àti láti mú dàgbà. Nígbà tá a bá dojú kọ àwọn nǹkan tó ń dán sùúrù àti ìfaradà wò, a lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àdánwò náà ká sì jẹ́ kó fún wa lókun tàbí ká máa bá a jà. Ó jẹ́ oun tí ó ṣòro láti gba àwọn àkókò tí ó le làti tún wa ṣe ṣùgbọ́n nígbàtí tí a bá làá kọjá, ó di nǹkan tí a se parí, èyítí ó dára jùlọ, ẹ̀yà ti Ọlọ́run tí ó gaju ara wa lọ, ó tó bẹ́ẹ̀.
Àwọn àbájáde ti Àwọn oun tí a yàn
Òtítọ́ tí ó le kán wà nígbàtí ó bá dé àwọn oun tí ayàn àti àwọn àbájáde tí ó tẹ̀le. Ní ìgbà gbogbo, àwọn Ìdánwò àti àwọn ìnira wa jẹ́ àbájáde bí àwọn mìíràn ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn àti pé a ń sé gbé ìgbésí ayé wa. A le jìyà bóyá nítorí ìwà ẹlòmíràn tàbí ìṣe sí tiwa. Díè nínú àwọn ìṣe sí wa jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àti pé tó bá jé bẹ́ẹ̀ní, àwọn àbájáde tí ó tẹ̀ le jẹ́ ohunkóhun bí kò ṣe oun tí ó dára.
Ìdojúkọ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Ọ̀tá
Nígbà tó bá dọ̀rọ̀ Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá wa nípa tẹ̀mí, a máa ń fún un láǹfààní tó pọ̀ jù tàbí ká máa gbé ga díẹ̀. Gbogbo ohun búburú tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa kìí ṣe ẹbí rẹ̀ ṣùgbọ́n ní òye pé ó kó ipa tó ga jù nínú àwọn ipò líle tí a dojú kọ.
Ní Ọjọ́ kẹta ti Ètò yìí, a yoo lọ sínú àwọn Ìwé-mímọ́ tí ó ní ìrètí tí yóò fihàn wa pé Ọlọ́run n ṣíṣe ní ìgbà gbogbo láti lo ohunkóhun àti ohun gbogbo fún oun rere wa àti láti ní ipa nínú àgbáyé.
Arò jinlẹ̀
- Ronú padà sí Ìdánwò tí o ti dojú kọ. Ṣé o rò pé ó jẹ́ Ìdánwò láti ṣe àtúnṣe ìhùwàsí rẹ, àbájáde oun tí o yàn, tàbí Ìdojúkọ àwọn òkùkù? Kọ àwọn èrò rẹ sílè.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A kò lè fẹ́ àwọn ìdojúkọ kù nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n nínú Ètò kúkúrú ọlọ́jọ́-4 yìí, a ó máa gbà wá ní ìyànjú láti mọ̀ pé a kò dá nìkan wà, pé Ọlọ́run ní ète fún ìrora wa, àti pé yíó lò ó fún ètò gíga Rẹ̀.
More