Líla Ìgbà Ìṣòro KọjáÀpẹrẹ

Going Through Hard Times

Ọjọ́ 1 nínú 4

Tújúká

Bí o bá ń la ìgbà ìṣòro kan kọjá nínú ayé rẹ báyìí, kìí ṣe ìwọ nìkan o. Kódà ìdá ọgọ́rùún nínú ọgọ́rùún ènìyàn ní àgbáyé ni yíó fi ojú kò iná ìṣòro tábí ìnira kan nínú ayé wọn. Bóyá o wà nínú ọkàn báyìí, ò ń jáde nínú ọkàn tàbí o tilẹ̀ ń wọ inú òmíràn, ara ìgbé-ayé ni. Kò sí ẹni tí ó fẹ́ràn láti la ìṣòro kọjá. Ronú nípa rẹ̀—ǹjẹ́ o ti pàdé ẹnìkan tí ó gbádún láti máa lá ìdojúkọ kọjá? Kò jọ bẹ́ẹ̀.

Kò sí òògùn tí a lè lò láti mú wàhálà jìnnà sí wa, kò sì sí ìye èrò rere tàbí ọ̀rọ̀ ìwúrí tí yíó pa igi dí ọ̀nà ìsòro ní ayé wa. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ lè jọ pé àwa nìkan ni à ń la ìṣòro kọjá, àwa nìkan kọ́.

A lè rí ìyànjú nínú ẹ̀kọ́ Jésù. Ó sọ fún wa ní Jòhánú 16:33 pé, “Ẹ ó ní ìpọ́njú.” Òye ohun tí a ó d'ojú kọ yé E—ayé tí ó kún fún ìríra, ẹ̀ṣẹ̀, ìkóríra, àti ọ̀tá ẹ̀mí tí ó fẹ́ pa wá run. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé Ó tún sọ fún wa pé a lè “tújúká” nítorípé “Ó ti ṣẹ́gun ayé.” A kò ní láti gbé ìgbé-ayé ìkárísọ nínú ayé tí ó ń bá'ni l'ọ́kàn jẹ́ yìí. A lè gbé ìgbé-ayé kíkún tí ó ní ìtumọ̀ pẹ̀lú òye wípé ní ìkẹyìn, a ó ní ìṣẹ́gun.

Jésù wá sí ayé fún ìdí kan—ọmọ-ènìyàn. Ó wá láti gbà wá là àti láti fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ṣì ń kọ́ pé bí a bá ti gba Jésù, tí a sì gbà Á bíi Olùgbàlà, îṣòro àti ìnira kò níí ya ilé wa mọ́. Irọ́ pátápátá ní èyí.

Kíka Ètò yìí kò níi mú òpin dé bá àwọn ìṣòro ayé rẹ, kò sì níi mú ọgbẹ́-ọkàn rẹ kúrò. Ohun tí a lèrò pé yíó ṣe ni pé yíó fún ọ ní okun díẹ̀ àti ìgboyà láti máa gbé àwọn ìgbésẹ tí ó kàn. O kò níílò láti gbé ìgbésẹ̀ ogún lónìí—ìwọ ṣáà ti gbé éyọ kan tí ó kàn. Bí ó bá sì di ọ̀la, ìwọ tún gbé òmíràn. A ó sọ nípa díẹ̀ nínú àwọn ìdí tí ó wà lẹ́yìn ìrora wa àti bí a ṣe lè la àwọn ọ̀nà ìpayà tí wọ́n bá kẹ́gbẹ́ kọjà.

A ní ìrètí pé bí a ṣe ń ṣe aáyan àkòrí yìí, ìwọ yíó mọ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ràn rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ tó, bí yíó ṣe lo ìnira rẹ fún ètò Rẹ̀, áti bí yíó ṣe yí ọ padà láti inú bọ́ sí òde. Ó ní ètò rere fún ayé rẹ, kódà nínú àtí láàrin ìnira rẹ. A gbà ọ́ ní ìyànjú pé kí o tẹ̀síwájú láti mọ́ ohun tí wọ́n jẹ́.

Ṣe Àṣàrò

  • Kíni ohun tí ó ń ṣelẹ̀ nínú ayé rẹ tí ó ń gba ọkàn rẹ kan? Kọ irú àbájáde tí o fẹ́ sílẹ̀.
Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Going Through Hard Times

A kò lè fẹ́ àwọn ìdojúkọ kù nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n nínú Ètò kúkúrú ọlọ́jọ́-4 yìí, a ó máa gbà wá ní ìyànjú láti mọ̀ pé a kò dá nìkan wà, pé Ọlọ́run ní ète fún ìrora wa, àti pé yíó lò ó fún ètò gíga Rẹ̀.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.