Líla Ìgbà Ìṣòro KọjáÀpẹrẹ

Going Through Hard Times

Ọjọ́ 3 nínú 4

Bí Ọlọ́run Ṣe Ń lo Àdánwò

Bí a ṣe ń la àwọn àkókò ìṣòro kọjá nínú ayé wa, yálà kí a dàgbà nínú rẹ̀ tàbí kí a má dàgbà. Kò sì sí à ń d'áni ní ẹ̀bi níbẹ̀ bí o bá ṣì bá ara rẹ nínú pé ò ń bá Ọlọ́run bínú nígbà tí ǹǹkan kò bá dẹrùn fún ọ. Gbogbo wa ni eléyìí ti ṣẹlẹ̀ sí rí. Ṣùgbọ́n bí a ṣe ń wá A, a ó rí I. Ọ̀nà kan tí a lè gbà mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa ń dàgbà láàrín àdánwò ni nígbà tí àwọn ìbéèrè“kíni ìdí” bá di ìbéèrè “báwo ni”fún wa.

Báwo ni O ṣe fẹ́ẹ́ lo èyí nínú ayé mi?
Báwo ní O ṣe fẹ́ẹ́ fi ọwọ́ tọ́ ẹlòmíràn látàrí àdánwò yìí?
Báwo ni O ṣe fẹ́ẹ́ mú ohun rere jáde nínú àjálú yìí?

Àṣamọ̀ ọ̀rọ̀ kàn wà tí a máa ń pa láàrin àwọn Krìstíẹ́nì pé Ọlọ́run kìí fi ohunkóhun ṣ'òfò. Òtítọ́ pátápátá tí ó kún fún ìrètí ni eléyìí. Bóyá a da wàhálà sí wa ní agbada ni tàbí àwa ní a fi ọwọ́ ara wa fa sùrútù, Ọlọ́run yíó lo ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ láti ra ayé wa páda, fí ọwọ́ tọ́ ẹlòmíràn, àti fún ògo Rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí Ọlọ́run ń fi ìrora wa ṣe.

Ó Ń Yí Wa Padà
Nígbà tí a bá ń jìyà nínú àdánwò gbígbóná janjan tí ó dùn ni dé ọkàn, ọ̀pọ̀ nínú wa kàn fẹ́ẹ́ “jẹ́ kí ó dé òpin ní kíá.” Ṣùgbọ́n kí á bà lè là wọ́n kọjá ní kíá, a gbọ́dọ̀ rìn kọjá nínú wọn. A ní láti fi ara da ìrora, kí a d'ojúkọ ohunkóhun tí ó ń dùn wá l'ọ́kàn kí a baà lè rí ìwòsàn ní òpin rẹ̀. Bí a ṣe ń la ìjì ayé kọjá, a ó di alágbára síi.

Ó Ń Yí Àwọn Ẹlòmíràn Padà
Ọ̀pọ̀ nínú wa ni ó ti fi ara da àdánwò tí ó jẹ́ pe wọ́n fún wa ní ìrírí tí a kò lè rí gbà ní ilé-ẹ̀kọ́. A lè má jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́-gboyè ṣùgbọ́n a ti di ògbóǹtarìgì nínú ìrora. Ọlọ́run rí èyí, Ó sì kà wá sí ohun-èlò Rẹ̀ láti ran àwọn élòmíràn lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù kọ ní 2 Kóríntì 1:3 pé Ó “ńtù wá nínú kí a baá lè tú àwọn ẹlòmíràn nínú.” Kí Í jẹ́ kí a dojúkọ àdànwó ti ó nira jú kí á baà lè sọ pé àwa la borí fúnraa wa. Rárá, ìfẹ́ ọkàn Rẹ̀ ni pé kí a mú nínú ìtùnú tí Ó fún wa kí a sì fi fún àwọn ẹlòmíràn.

Róòmù 8:28 sọ wípé“nínú ohun gbogbo” Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ fún ire. Kìí ṣe nínú àwọn ohun kan tàbí nínú ohun díẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo ni. Ọlọ́run mú àjálù tí ó burú jù tí ó lè ṣẹlẹ̀—ikú Jésù lórí àgbélébúú—Ó sì lòó fún ire tí ó ga jú—ìgbàlà gbogbo aráyé. Bí ìrora bá ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni àǹfáání ṣe pọ̀ tó fún ìràpadà Ọlọ́run láti fi ara hàn tẹ̀yẹtẹ̀yẹ. Pẹ̀lú ìtàn ìràpadà kọ̀ọ̀kan, Ọlọ́run ń gba ògo fún bí Ó ṣe yí àjálú nínú ayé wa padà sí ìṣẹ́gun.

Ní ọjọ́ tí ó gbẹ̀yìn nínú Ètò-èkọ́ yìí, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí rẹ̀ tí àwọn àkókò ìdojúkọ wa ṣe maá ń pẹ́ ju bí a ṣe fẹ́ lọ. Àti nínú ìrètí, a ó kọ́ bí a ṣe lè gbẹ́kẹ̀lẹ́ Ọlọ́run síi kí a sì mú ìgbàgbọ́ wa dágbà.

Ṣe Àṣàrò

  • Kíní àdánwó tí ó lè jù tí o ti là kọjá? Báwo ni o ṣe lè lo ìrora rẹ láti ràn ẹlòmíràn lọ́wọ́?

Ìwé mímọ́

Day 2Day 4

Nípa Ìpèsè yìí

Going Through Hard Times

A kò lè fẹ́ àwọn ìdojúkọ kù nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n nínú Ètò kúkúrú ọlọ́jọ́-4 yìí, a ó máa gbà wá ní ìyànjú láti mọ̀ pé a kò dá nìkan wà, pé Ọlọ́run ní ète fún ìrora wa, àti pé yíó lò ó fún ètò gíga Rẹ̀.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.