Wíwá Àyè Fún ÌsinmiÀpẹrẹ

Ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Láti Lè Bùfún Ẹlòmíràn.
Níní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀mí kò ju báyìí lọ — jíjọ̀wọ́ gbogbo ìṣẹ̀dáà mi sì ìkápá agbára rẹ̀. Nígbà tí a bá ti jọ̀wọ́ ẹ̀mí fún Ẹ̀mí Mímọ́, Ọlọ́run fúnrarà yóò kún-un. — Andrew Murray
Ìdí tí a fi nílò ìsinmi jẹ́ nítorí a ti ń ṣiṣẹ́ tàbí a ti ń sapá lọ́nà kan tàbí òmíràn. Àti wípé nítorí a ti kọ́ bí a tií sinmi àti wà ní ìsinmi, kò túmọ̀ sí wípé bí a óo tiwa nìyí.
A ó padà ṣiṣẹ́.
A ó padà ran àwọn míràn lọ́wọ́.
A ó ṣì padà ní ìrẹ̀wẹ̀sì.
Káa kàn máa sinmi lásán kòní ìtumọ̀. A ń sinmi a sì ń wá ìsinmi kí a báa le padà sẹ́nu iṣẹ́. Ó ní àádùn tó wà nínú iṣẹ́ tí a tẹ̀lé pẹ̀lú ìsinmi; nínú kíkún fún agbára láti fi ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ìsinmi.
Bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, ṣíṣe ìjíròrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣíṣe àkọsílẹ̀, àti pípa àwọn ohun tó lè fa ìdíwọ́ tì jẹ́ àwọn ǹkan tí máa fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára lẹ́yìn ìsinmi. À óò rí ìsinmi bí a tií ṣe èyí lójojúmọ́. Gẹ́lẹ́ bí ara wa ti nílò ọ̀pọ̀ọ wákàtí láláalẹ́ láti mú ara wa bọ̀ sípò, bẹ́ẹ̀ ni èmi wà nílò rẹ̀ pẹ̀lú tí nílò ìsinmi. A kò lè retí láti ní ẹ̀mí tó lágbára, láì fi kún ìṣúra rẹ̀. A kò lè nírètí wípé ìsinmi ọ̀sẹ̀ kan máa tó wa fún iṣẹ́ẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù A ní láti máa ṣe ìfárajìn ìsinmi olójojúmọ́. A sì ni láti máa ṣe àkíyèsí tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ti ń wọlé wá.
Nínú ìwée rẹ̀, Dídarí Pẹ̀lú Kòròfo: Bíbù sí Ìṣúra Ìtara Wa, òǹkọ̀wé àti olùṣọ́àgùntàn Wayne Cordeiro sọ nípa àlá kan tí ó ní. Obìnrin kan tọ àgbè kan lọ nínú oko rẹ̀ láti bèrè fún ohun kan, èyí tí àgbẹ̀ náà kò ní lákòókò náà. Àgbè náà sì dáhùn wípé, "Padà wá lọ́la, n óò ti ní ọ̀pọ̀ nígbà náà." Obìnrin yìí fajúro ṣùgbọ́n àgbẹ̀ náà kò bìkítà. Ṣe ni ó ń ṣiṣẹ́ẹ rẹ̀ lọ. Nígbà tí ẹyin tàbí wàràa oko rẹ̀ bá ti tán tí àwọn ènìyàn sì ń wá láti bèrè lójojúmọ́, àgbẹ̀ náà yóò kàn wípé, "Padà wá lọ́la, n ó ti ní síi." Olùṣọ́-àgùntàn Cordeiro wá fi ìrísí titun tí ó ní lẹ́yìn àlá náà hàn báyìí:
N kò nílò láti máa fúnra mi ní gbèdéke tí a kò fojú rí, làálàá ojoojúmọ́ láti ṣe síi, tàbí láti ṣiṣẹ́ ju ọ̀sẹ̀ tó kọjá lọ. Àkókò kanńà la fifún mi ní òòjọ́, mo sì fẹ́ ṣe ìgbìyànjú pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Nígbà tí ọjọ́ bá sì parí, n óò wàá sọ wípé, "Padà wá lọ́la, n óò sì ti ní síi.”
A máa ń jí lójojúmọ́ pẹ̀lú okun tí ara àti ẹ̀mí tó ní ìdiwọ̀n. Nígbà tí a bá sì lo gbogbo okun tí a ní yìí tán, àsìkò tó fúnwa láti sinmi nìyẹn. Ní àkókò báyìí tí okun wa ti pin, ipá kan kò sì mọ́ láti tako iṣẹ́ẹ Rẹ̀ nínú wa.
Fẹ̀yìn tì, dúró, kí o sì sinmi. Ìgbà tíó sunwọ̀n jù fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run nìyí.
Gba èyí rò
- Ǹjẹ́ o lérò wípé ó nílò láti bá gbogbo àìní tobá kojúù rẹ pàdé?
- Kí ni ǹkan tí olè múwọ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ láti ní ìmúbọ̀sípò?
- Kọ ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fi hàn ọ́ nípasẹ̀ ẹsẹ̀ Bíbélì tàbí ètò Bíbélì tío kà lónìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.
More