Wíwá Àyè Fún ÌsinmiÀpẹrẹ
Ṣe Àṣàrò Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Bí o ti ń ka Bíbélì síi; tí o sì ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóò ti máa yà ọ́ lẹ́nu síi. — Charles Spurgeon
Ọ̀pọ̀ ọmọ lẹ́yìn Krístì ni kò ní ìmọ̀ tíó péye nípa ìtumò àṣàrò. Nígbà tí a bá ńṣe àṣàrò lórí ohun kan kò jù wípé à ń pa èrò wa pọ̀ sórí ǹkan yẹn. Fún wa láti ní ìmọ̀ síi nípa ṣíṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, e jẹ́kí a ka àpèjúwe tí Olùṣọ́àgùntàn Rick Warren ṣe. Ó ní, “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ wípé, tí o bá máa ń ní ìpòrúru ọkàn, o ti mo bí a ti ńṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìyẹn. Ìpòrúru ọkàn jẹ́ rírọ èrò búburú sí ọ̀tún àtòsì. Nígbà tí o bá mú ẹsẹ̀ Bíbélì mélòó kan tí o sì bẹ̀rẹ̀ síí gbàá rò sí ọ̀tún àtòsì, àṣàrò ni à ń pe èyí.”
Bíbélì mẹ́nu ba àṣàrò nígbà a ogún-ólé ó sì wá rọ̀wá láti máa ṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìṣe tíó dára ní èyíí ṣe láti mú wọ àkókò ìbápàdé wa pẹ̀lú Ọlọ́run lójojúmọ́ nítorí ó ń pèsè ìsinmi tí ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ìdàgbàsókè nínú ẹ̀mí.
Bí a ti ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ka Bíbélì lójojúmọ́, a lè ri ara wa bọ inú àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí káa si bẹ̀rẹ̀ sí ní bá Ọlọ́run jíròrò. Láti lè mọ bí a ti lè ṣe àṣàrò lórí ẹsẹ̀ Bíbélì kan tàbí méjì, ẹ jẹ́kí a tú Éfésù 4:31-32 palẹ̀ tíó kà báyìí, “Ẹ ní láti mú gbogbo inú burúkú, ìrunú, ìbínú, ariwo àti ìsọkúsọ kúrò láàárín yín àti gbogbo ǹkan burúkú. Dípò èyí, ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú, kí ẹ sì máa dáríji ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti dáríji yín nípasẹ̀ Krístì.”
Ẹ jẹ́kí a kàá lẹ́ẹ̀kan si kawá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wípé:
Ǹjẹ́ èmi ní inú burúkú?
Ṣé ènìyàn òníìbínú ni èmi ńṣe?
Ṣé ọ̀rọ̀ mi máa ń mú ariwo dání?
Ṣé mo ní ojú àánú?
Ǹjẹ́ mo máa ń dáríji àwọn tó ṣẹ̀ mí láì yísẹ̀ padà?
Lẹ́yìn èyí laó wà dúró láti tẹ́tí sí, ohùn Ọlọ́run tó tutù ṣùgbọ́n tí ń wá pẹ̀lú agbára. Ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ẹ nì tí a maá fẹ́rẹ̀ má lè gbọ́ọ, ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe ìdíwọ́ fúnwa láti mọ ohun tíó ń báwa sọ. A lè gba àwọn àṣàrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí láàyè bí a ti ńṣe iṣẹ́ òòjọ́ wa tí yóò sì máa pè wá sí àkíyèsí àwọn ìkorò, ìbínú, ariwo, ọkàn líle, tàbí àìní ìdáríjì tó lè fẹ́ já èròo wa gbà.
Ṣíṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni èyíí ṣe.
Òtítọ́ Bíbélì a máa rinlẹ̀ nínú ọkàn-àyà wa nígbàtí a bá ńṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àṣàrò a máa pèsè ipele ìsinmi titun fúnwa nítorí gbogbo ipa ọpọlọ wa ni a ti fi ń ronú nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọkàn yóò sì ní òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn ayé yìí. Kìí ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n a ní agbára láti mú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń yí ìgbésí-ayé ẹni padà tí ó tọ ayée wa wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbàtí a bá gbìyànjú báyìí, kòsí bí a kò ṣe ní dé ibi tí Ọlọ́run fẹ́ mú wa lọ.
Gba èyí rò
- Yan ẹsẹ̀ Bíbélì kan látinú ètòo tòní, tàbí òmíràn tíó bá wùọ́, kóo sì ṣe àṣàrò lórí rẹ̀. Bí o ti ń kàá, béèrè pé kí Ọlọ́run fi àwọn ibi tí ìwọ ti ń gbọ́ràn hàn ọ́ àti àwọn ibi tí o ti nílò àtúnṣe fún ìdàgbàsókè nínú ẹ̀mí. Jẹ́kí àwárí titun yìí gba èrò rẹ kan jálẹ̀ ọjọ́ náà.
- Kọ ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fi hàn ọ́ nípasẹ̀ ẹsẹ̀ Bíbélì tàbí ètò Bíbélì tío kà lónìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.
More