Wíwá Àyè Fún ÌsinmiÀpẹrẹ

Making Time To Rest

Ọjọ́ 4 nínú 5

Mú Ìdíwọ́ Kúrò Lọ́nà.

Tí o kò bá wà àyè kúrò nínú làálàá ọjọọjọ́ ní àyíkáà rẹ, kòókòó àyíká rẹ yóò fà ọ́ lulẹ̀. — Erwin McManus

Ọ̀kan nínú àwọn àlàyé ìtumọ̀ ìsinmi ni jíjẹ́ òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn tàbí ìdojúrú. Ní àsìkò yìí nínú ayée wa, a kò nílò láti rìn jìnà ka tó bá àwọn ǹkan tí yóò mú ìsinmi wá dojúrú tí yóò sì mú àníyàn wá pẹ̀lú. Àwọn ǹkan wọ̀nyí ní àsìkò yí lè dà bí ohun tí a kúndùn tó sì ń mú ìtura wá, ṣùgbọ́n níkẹyìn, ṣeni iná ìsinmi wa tún ń jó lọlẹ̀.

Àìníye ènìyàn ni ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí afi lè yẹ̀bá fún hílàhílo ayé. Ọ̀pọ̀ ìwé, àkọsílẹ̀, ọ̀rọ̀-ìyànjú, àti ìwàásù ló ti sọ nípa àwọn àṣírí ọ̀nà tí a fi lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ǹkan tí ń fi àkókò ẹni ṣòfò. Ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun kan náà níí fi àkókò gbogbo ènìyàn ṣòfò. Ohun tó ń fa ìpèníjà ìfàkókò ṣòfò fún ẹnìkan kìíṣe ìpèníjà f'ẹ́lòmíràn. 

Fún wa láti bọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìdíwọ́ ayée wa, a ní láti gbé àwọn ǹkan mélòó kan yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, a ní láti dá ohun tí ń fi àkókò wa ṣòfò mọ̀. Àwọn ǹkan tó ń mú wá pá ohun pàtàkì tì bóyá nítorí ó dà bíi wípé ó ṣe pàjáwìrì tàbí ó jẹ́ ohun tí a kúndùn láti máa ṣe. Èkejì, a ní láti ṣe ìpinnu àti kọ àwọn ètò kan sílẹ̀, bíi àwọn tó lè mú kí àwọn ènìyàn tó ṣe pàtàkì nínú ayée wa dàbí ìdíwọ́. 

Ohunkóhun tí ǹkan náà lè jẹ́ tó ń kó àlàáfíà àti ìsinmi wa lọ, a ní láti fi ìjánu síi. Óṣeéṣe bí o ti ń ka ètò yí, kí ǹkan tó jẹ́ ìdíwọ́ tí sọ síọ lọ́kàn. Kàkà kí a gba ìdíwọ́ láàyè láti gba ìsinmi àti àwọn ènìyàn tó ṣe pàtàkì nínú ayée wa kúrò, a lè gbìyànjú láti…

  • ...má ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá nígbà tí àwọn ọmọ wa kò ba tíì sùn. 
  • ...yàn láti fi àwọn ohun réré inú ayée wa ṣe àfojúsùn dípò gbígba ìpèníjà inú ayé láti jẹ́ ìdíwọ́ fúnwa. 
  • ...gbé gbogbo ìpè ẹbí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kí a sì jẹ́ kí àwọn tó kù lọ sínú ẹ̀rọ tí ń ṣe àkáálẹ̀ ọ̀rọ̀. 
  • ...má wo ẹ̀rọ amówùn-máwòrán títí di ìpárí ọ̀sẹ̀. 
  • ...pa àwọn àníyàn ètò ọjọ́ iwájú tì kí a báa lè gbé fún àkókò yí. 
  • ...fi ìdiwọ̀n sí ìwọ̀n àkókò tí a ó máa lò lórí àwọn ẹ̀rọ ayárabíàṣá àti àwọn ẹ̀rọ ìdárayá.  

Tí a bá ń bá ara wà nínú àníyàn àti ìpòrúru ọkàn lóòrè-kóòrè, a ní láti dín àwọn ǹkan tí ó ń fa èyí tàbí ká mú wọn kúrò ráúráú. Kò ní rọrùn. Ohunkóhun tó tóó ní nílòo iṣẹ́ ati igbinyanju. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ mìíràn wà tí a máa gba ìdíwọ́ inú ayé kankan láyè láti gba ìsinmi Ọlọ́run tí ó dára jù kúrò lọ́wọ́ wa. 

Gba èyí rò

  • Kíni ohun náà tí máa ń sábà fa ìdíwọ́ fún ìsinmi tí ó péye fún ọ?
  • Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo nílò láti gbé lónìí láti lè dín àwọn ìdíwọ́ wọ̀nyí kù tàbí mú wọn kúrò pátápátá?
  • Kọ ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fi hàn ọ́ nípasẹ̀ ẹsẹ̀ Bíbélì tàbí ètò Bíbélì tío kà lónìí.
Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Making Time To Rest

Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò yí.