Wíwá Àyè Fún ÌsinmiÀpẹrẹ

Making Time To Rest

Ọjọ́ 1 nínú 5

Kí ni ó túmọ̀ sí láti sinmi?

Bí oṣù kan ti ń tẹ̀lé òmíràn ni àwọn ètò iṣẹ́ẹ wa ń ga síi. Nígbà tí a bá gbìyànjú láti kórajọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, ni ẹnu yóò wá yàwá tí a bá ri wípé kò sí àyè fún bíi oṣù kan. Ojúṣe wa sí àwọn ọmọ wa wà níbẹ̀, ohun ṣíṣe nínú ìjọ, àwọn ètò ibiṣẹ́, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, àti àwọn ìrìn àjò fún ìsinmi. Gbogbo ìgbésí ayée wa ni a ti ṣètòo rẹ̀ tíó sì kún fọ́fọ́ láì fi àyè sílẹ̀ fún ohunkóhun tó lè mú wa bọ̀sípò àti fún wa ní ìsinmi pẹ̀lú. 

Lọ́pọ̀ ìgbà la máa ń rò pé ìsinmi túmọ̀ sí ìmẹ́lẹ́. Èyí túmọ̀ sí wípé a lè wà nílé láì ṣe ohun kankan. Lótìítọ́ irú ǹkan báyìí lè wà nínú àkókò ìsinmi wa. ṣùgbọ́n kìí ṣe kìkì dá rẹ̀ 

Ìsinmi nííṣe pẹ̀lú ìmúbọ̀sípò.
ó nííṣe pẹ̀lú mímọ ìgbà tí ó ti rẹ̀ wá, tí a ti lo arawa yọ́, tí a sì nílò láti mí kanlẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó nííṣe pẹ̀lú mímọ ìdiwọ̀n wa àti bí a ti ńṣe àwọn ojúṣe òòjọ́ wa. Fún àgọ́-ara wa láti ní ìmúbọ̀sípò tíó péye, a nílò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsinmi, èyí tí kò yọ orun àṣálẹ́ tíó péye sílẹ̀. Tí a bá ríi wípé ó máa ń rẹ̀ wá lọ́pọ̀ ìgbà, ohun ọlọgbọ́n ni yóò jẹ́ fúnwa láti ṣe àgbéyẹ̀wò iye àkókò orun tí a ń sùn lójojúmọ́.

Ìsinmi nííṣe pẹ̀lú ìtura. 
Ó nííṣe pẹ̀lú mímọ ohun tí ń rówa lágbára àti àwọn ǹkan tí ń jo ìṣúra agbára wa. Ó nííṣe pẹ̀lú yíyan àwọn ìdáwọ́lé tàbí ìdákẹ́rọ́rọ́ tí yóò mú ìsọdọ̀tun bá ẹ̀míi wa. Tí a bá tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe àwọn ǹkan tó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì báwa dípò àwọn ǹkan tí yóò ró wa lágbára, a ó kàn máa wo ìtura lókè réré ni kò ní wá bá wa. A ní láti fi kún ìṣúra ìtura yìí dípòo mú kúrò nínú rẹ ní àwọn àkókò ìsinmi wa.

Ìsinmi nííṣe pẹ̀lú ìsọdọ̀tun. 
Ó jẹ́ níní ìsọdọ̀tun tíó jinlẹ̀ ní gbogbo ìpín ayée wa. Ó jẹ̀ lílo akókò pẹ̀lú Ọlọ́run kí a báa lè sọ wá dọ̀tun nínú ẹ̀mí. Lótìítọ́ a lè kúndùn láti máa ṣe àwọn ǹkan tí yóò sọ ọpọlọ wa dọ̀tun, ju gbogbo rẹ̀ lọ, a nílò ìsọdọ̀tun ẹ̀mí nípa fífi àyè sílẹ̀ láti lò pẹ̀lú Ọlọ́run lójojúmọ́. 

Fún ọjọ́ mẹ́rin sí, a ó máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a fi lè ṣe àwárí ìsinmi fún ara, ọkàn àti ẹ̀míi wa. A óò kọ́ bí a ti ńṣe àwọn ètò tí yóò mọ́ wa lára lójojúmọ́. Nípasẹ̀ ṣíṣe èyí, a máa bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò lọ síbi tí a ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọpọlọ, ẹ̀mí àti ara nínú ayée wa.

Gba èyí rò

  • Nígbà tí o bá ń ronúu gbígba ìsinmi, ǹjẹ́ ó máa ń dà bíi ohun tí kò ṣeéṣe? 
  • Ipele ayéè rẹ wo ni o lérò wípé ó nílò ìsinmi jùlọ? Ara, ọkàn, tàbí ẹ̀mí?
  • Kọ àwọn ohun tí Ọlọ́run bá fihàn ọ́ nípasẹ̀ ẹsẹ̀ Bíbélì tàbí ètòo Bíbélì tío kà lónìí.
Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Making Time To Rest

Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò yí.