Wíwá Àyè Fún ÌsinmiÀpẹrẹ

Making Time To Rest

Ọjọ́ 3 nínú 5

Sọ Ọkàn Rẹ Dọ̀tun Nípa Ṣíṣe Àkọsílẹ̀.

Ohunkóhun tí o bá ń ronú nípa rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ si lọ́kàn rẹ. Máse fi àwọn ohun tí ò ń là kọjá ṣe àfojúsùn rẹ. Fi ọkàn rẹ sí àwọn ohun tí ìwọ ńṣe lọ́wọ́! — Dr. Caroline Leaf

Ni ojo keji ètò yìí, a kọ́ wípé ọ̀nà kan tí a fi lè ní ìsinmi jẹ́ ṣíṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí àwọn ìgbésẹ̀ wa lè wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn Ọ̀títọ́ọ Rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà láti gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàyè láti wọnú ẹ̀mí wa lọ. Òtítọ́ọ Rẹ̀ ma gba ọkàn wa kan á ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ohun gbogbo ní ọ̀nà ọ̀tọ̀. Bí a ti ń ṣe àṣàrò nínú Ọrọ Ọlọ́run, ẹ̀míi wa yóò ní ìsọdọ̀tun àti wípé a óò rí ìsinmi tí a kò lérò gbà.

Láti lè rí ohun tí ó dára jù gbà l'àkókò àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè fi ṣíṣe àkọsílẹ̀ ojoójúmọ́ pẹ́ẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́. Tí èyí bá jẹ́ ohun àjòjì sìwa kò pọn dandan fúnwa láti máa ṣe àkọsílẹ̀ lójú méjèèjì. A lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkọ ọ̀rọ̀ bíi ilà méjì pẹ̀lú ìmísí tí a rígbà bí a ti ń ka Bíbélì. Ogunlọ́gọ̀ ọ̀nà ló wà láti ṣe àkọsílẹ̀. A lè kọ èrò ọkàn tàbí àdúràa wa sílẹ̀; kódà àwọn ẹlòmíràn a máa ya àwòrán ní àkókò tí wọ́n ńṣe àkọsílẹ̀. Kò sí ọ̀nà kan gbòógì tí wọ́n fi ń ṣeé. Láti ràn ọ́ lọ́wọ́ fún ìṣísẹ̀ rẹ àkọ́kọ́, ìlànà kan tí ó rọrùn láti tẹ̀lé nìyí: 

  • Yan ẹsẹ̀ Bíbélì kan (ó sì lè ju ọ̀kan lọ) kí o sì kàá. 
  • Kàá lẹ́ẹ̀kan si. 
  • Kọọ́ sílẹ̀. 
  • Bèrè fún ìmísí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kosì kọ èyí sílẹ̀ pẹ̀lú.

Bóyá Róòmù 8:28 lo pinu láti ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ èyí tí ó sọ wípé, “Àwa sì mọ̀ wípé nínú ohun gbogbo Ọlọ́run ń ṣíṣe kí ǹkan yọrí sí rere fún àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí a pè nípasẹ̀ ètòo Rẹ̀.” Lẹ́yìn tí o bá ti Kàá ní ẹ̀mejì sí mẹ́ta, a ó wá kọọ́ sílẹ̀. A tún lè gbìyànjú láti kọọ́ sílẹ̀ láti inú àwọn oríṣiríṣi ètò ògbùfọ̀ Bíbélì tí ó wà. A ó mú àkókò àkọsílẹ̀ náà wá sí ìparí nípasẹ̀ bíbéèrè fún ìmísí Ọlọ́run lórí àwọn ǹkan tí a ṣẹ̀ kà tán.

Bí a ti ń kà Bíbélì pẹ̀lú ìlànà tí a ti fúnwa ṣáájú, a lè fi sí oókan àyà wa jálẹ̀ ọjọ́ náà. Ṣíṣe àkọsílẹ̀ lójojúmọ́ tún máa ràn wá lọ́wọ́ láti rí ipasẹ̀ ìrìn-àjò ìgbàgbọ́ wa bí a ti ń tẹ̀síwájú àti àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run ti fi kọ síwa ní ìgbà kan. 

Ìmọ́lẹ̀ yóò tàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan àti wípé a ó ní ìrísí titun gbà nípa bí a ti ń mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò nínú ayée wa yóò sì tún mú wa bọ̀sípò láti ìta dé inú. Àti wípé pẹ̀lú ìsọdọ̀tun ẹ̀míi wa yìí, à ń rí ìsinmi tí ìgbádùn kankan ní ayé yìí kò lè fún ni. 

Gba èyí rò 

  • Ǹjẹ́ ìwọ ti fi ìgbà kankan ṣe àkọsílẹ̀ rí nínú ìrìn-àjò òòjọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run?  
  • Yan ẹsẹ̀ Bíbélì kan kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ìlànà tí ati ṣàlàyé ṣáájú. 
  • Kọ ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fi hàn ọ́ nípasẹ̀ ẹsẹ̀ Bíbélì tàbí ètò Bíbélì tío kà lónìí.
Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Making Time To Rest

Isé àsekúdórógbó àti isé lemólemó jé ohun tí a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún ní Ayé wa, àtipé ó lè jẹ́ ìpèníjà láti simi. Kí a bá lè se ojuse wa àti àwon ètò lónà tó já fáfá, a gbódò kọ́ láti sinmi tàbí a kò ni ní ohunkóhun tó máa sékù láti ṣètìlẹyìn fún àwon tí a féràn àti sí àwon ìlépa tí a gbé kalẹ̀. Ẹ jé kí a lo ọjọ́ márùn-ún tó tè lé fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsimi àti bí a se lè fi ohun tí a kọ́ sí inú ayé wa.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò yí.