Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé RẹÀpẹrẹ
Bóyá nínú ilé tàbí lẹ́nu iṣẹ́, nínú ìgbìmọ̀ ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí, gbogbo wa lati kọ́ bí a tií gẹ̀rẹ́ẹ̀sì ìhùwàsí wa. Bí a tií jókòó dáadáa. Bèrè ǹkan pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Wọ aṣọ tó tọ́. Àti ṣe ohun tó tọ́.
Síbẹ̀, lẹ́ẹ̀ kànkan, a ma ńsọ tàbí ṣe àwọn ǹkan tí kò mọ́pọlọ dání. Bí ìgbà tí ǹkan bá kún tó sì ru dànù ní tií rí—ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbínú. Lẹ́yìn gbogbo rẹ̀ a lè máa bèrè wípé, "Báwo ni iru ǹkan yìí ti tẹnu mi jáde?!"
Ṣùgbọ́n ǹkan tí a mọ̀ ni, ìyẹn tí a bá jẹ́ olóòótọ́ tí a sì ṣe tán láti kojúu rẹ̀. Àti inú wa ló ti ń ṣẹ̀ wá. Jésù àti Ọba Sólómọ́nì ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ohun tí ń gbé inú ọkàn wa ni kùdìẹ̀-kudiẹ.
A nílò irin-ìdáàbòbò fún ọkàn wa. Nítorí, paríparí ẹ̀, ìwà (tí a wù síta) ló máa fi ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn hàn.
Àwọn ìmọ̀lára mẹ́rin ló lè máa ta ẹ̀rí-ọkàn wa lólobó. Ó yẹ kí olobó yìí máa mú wa yẹ ọkàn wa wò lóòrè-kóòrè. Àwọn ìmọ̀lára yìí sì ni ẹ̀bi, ìbínú, wọ̀bìà, àti ìlára.
Ẹ̀bi a máa sọ wípé, "Mo jẹ ọ́ ní gbèsè." Mo jẹ ọ́ ní gbèsè nítorí mo gba ohun kan kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ní ìdáhùn sí ẹ̀bi, jẹ́wọ́. Jẹ́wọ́ fún ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kàn; tan ìmọ́lẹ̀ síi.
Ìbínú a máa sọ wípé, "O jẹ mí ní gbèsè." O sẹ̀ mí tàbí ó gba ǹkan lọ lọ́wọ́ mi. Ní ìdáhùn sí ìbínú, ṣe ìdáríjì. Dáríji ẹni tó ṣẹ̀ ọ́. Tú wọn sílẹ̀.
Wọ̀bìà a máa sọ wípé, "Mo jẹ araà mi ní gbèsè." Wọ̀bìà a máa lérò wípé gbogbo ejò jíjẹ ni. Ní ìdáhùn sí wọ̀bìà, fi fúnni. Ní ìyípadà sí ẹni tí ń fi fúnni tọkàntọkàn. Láì bèrè ohun kan. Láì ni ìkùnsínú.
Ìlára a máa wípé, "Ayé jẹ mí ní gbèsè." Ẹlòmíràn ti gba ohun/ẹni tó tọ́sí mi. Ní ìdáhùn sí ìlára, bọlá fún omolàkejì rẹ. Kọ ìwé pélébé sí wọn. Kí wọn kú oríire fún ohun tí ń fa ìlára yìí gan.
Nígbàkigbà tí a bá kọlu àwọn ìrìn-ìdáàbòbò ìmọ̀lára wọ̀nyí, a nílò láti ṣe àkíyèsí. Wọ́n ń ta wá lólobó sí aburú tó ń bọ̀ ni. Tí à kò bá ṣe àkíyèsí àbámọ̀ ń dúró dè wá.
Tí ó bá gbádùn ètò yí, wo àwòrán àgbéléwò ti Andy Stanley márùn-ún nípa irin-ìdáàbòbò - pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ àwòrán ọ̀fẹ́ irúu rẹ̀ lóríi ẹ̀kọ́ Bíbélì - ní http://anthology.study.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìbá tí rí bí a bá ní iru irin í dáàbò bayi ninu àjọṣe wá, ìdọ́kòwò wá, àti isé wá? Báwo ni wọn yóò rí? Kí ni wọn ṣe lè pá wá mọ kúrò lọ́wọ́ ìkábàmọ̀? Fún ìwọ̀n ojo márùn-ún láti òní, ẹ jẹ ki a gbe bí a ṣe lè fi irú irin í dáàbò bayi sì ayé wa yẹ̀ wò.
More