Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé RẹÀpẹrẹ
Oníkálukú wa ló mọ ẹnìkan, jẹ́ ẹnìkan, tàbí jẹ́ ẹni tí yóò tọ́ ẹnìkan tí ìgbésí ayée rẹ̀ yóò yàtọ̀ gedegbe kání wọ́n fi irin-ìdáàbòbò sípò láti pawọ́n mọ́ kúrò nínú ìwà àìmọ́ ti ìbálòpò.
Pípa ara ẹni mọ́ báyìí kìí ṣe ohun tó gbajúmọ̀. Kódà, kò sí ibòmíràn tí àṣà ti ká wa lọ́wọ́ kò bíi èyí (tí yóò sì bá wa wí nígbà tí a bá kùnà) ju ti ìlàkalẹ̀ ìwà híhù lásán. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ma ń wo ère àgbéléwò, gbọ́ orísirísi orin, tí a sì ti kà àwọn ìwé tó bọlá fún ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń fi èyí dára yá. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá ṣẹlẹ̀ lójú ayé . . . tí ẹnìkan táa mọ̀ ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ́ yìí? Ṣeni yóò rẹ̀wá sára.
Nítorí náà, ìkìlọ̀ ré: àṣà yóò máa ṣiṣẹ́ lòdì sí gbogbo ìgbìyànjú rẹ láti fi irin-ìdáàbòbò ìwà-híhù sípò. Ṣùgbọ́n nínú ẹsẹ̀ẹ Bíbélì tòní, Pọ́ọ̀lù àpọ́sítélì ṣe àlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣe pàtàkì.
Ó sọ wípé ìwà àìmọ́ ti ìbálòpọ̀ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ tó fi ńwó ayé ènìyàn palẹ̀. Kódà, Ó fisí ipele ọ̀tọ̀, wípé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ "lòdì sí ara [ẹni]." Lọ́rọ̀ kan, ohun búburú ni yóò tẹ̀yin rẹ̀ yọ fún ẹni tíẹ jọ dá ẹ̀ṣẹ̀ náà àti ìwọ fúnra rẹ. Paríparí rẹ ni wípé, kò sí bí o tilè bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà tí yóò tẹ̀yin rẹ̀ jáde. Óṣeéṣe fún ọ láti ni ìmúbọ̀sípò ọrọ̀ tí o pàdánù. Óṣeéṣe fún ọ láti tún dìde padà nígbà tobá fàsẹ́yìn lẹ́nu ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n tóbá nííṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀, ọ̀tọ̀ làyèe rẹ̀. Ǹjẹ́ o lè rí ìdáríjì gbà bí? Ní gbogbo ọ̀nà. Èyí kò dí ìtẹ́wọ́gbà àti Ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ lọ́wọ́. Ǹkan kan pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ ni wípé, kò sí àyè láti ṣe àtúnṣe.
Kí gan, wá ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù? "Ṣá àsálà . . ."
Sèbí ohun tí gbogbo ọkọ mafẹ́ kí ìyàwó wọ́n ṣe nìyí? Ohun tí gbogbo aya mafẹ́ kí ọkọ wọ́n ṣe? Ohun tí gbogbo arákùnrin mafẹ́ kí àbúrò wọ́n obìnrin ṣe? "Sá fún gbogbo ìwà àìmọ́ tí ìbálòpọ̀."
Báwo ni atilè fi èyí ṣe irin-ìdáàbòbò tara ẹni? Ẹ jẹ́ kaṣe àgbéyèwò àlàyée Jésù nípa ẹ̀ṣẹ̀, a óò wá rí ohun tó nííṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀. Jálẹ̀ iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀, Jésù fi kọ́ni wípé ohun dídára tí abá lè ṣe fún ọmọlàkejì wa ni ǹkan tó dárajù. Nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀, jẹ́ ohunkóhun tí kò bá poju òṣùwọ̀n yí. Nígbà-kigbà tí mo bá fi èmi ṣaájú ìrẹ dójú ìpalára fún ọ, ẹ̀ṣẹ̀ ni èyí. Ìgbà-kigbà tí o bá fi araà rẹ ṣáájú mi dójú ìpalára fún mi, ẹ̀ṣẹ̀ ni èyí.
Torí náà, ó yẹ kí irin-ìdáàbòbò fún ètò-ìbálòpọ̀ wa máa kówa ní ìjánu kúrò ní ìdíi ṣíṣe ìjàmbá fún ọmọlàkejì wa. Ǹjẹ́ yóò mú ìtìjú báwọn? Ǹjẹ́ yóò di àṣírí tí wọn kòlè bá ẹnikẹ́ni sọ jálẹ̀ ayée wọn? Ǹjẹ́ ó lè fa ìjákulẹ̀ nínú àwọn ìbáṣe wọn lọ́jọ́ iwájú? Nítorí náà, bí Pọ́ọ̀lù ti sọ , "sá àsálà."
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìbá tí rí bí a bá ní iru irin í dáàbò bayi ninu àjọṣe wá, ìdọ́kòwò wá, àti isé wá? Báwo ni wọn yóò rí? Kí ni wọn ṣe lè pá wá mọ kúrò lọ́wọ́ ìkábàmọ̀? Fún ìwọ̀n ojo márùn-ún láti òní, ẹ jẹ ki a gbe bí a ṣe lè fi irú irin í dáàbò bayi sì ayé wa yẹ̀ wò.
More