Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé RẹÀpẹrẹ

Guardrails: Avoiding Regrets In Your Life

Ọjọ́ 4 nínú 5

Nígbà tí o bá ń ronú nípa àwọn irin-ìdáàbòbò tí ìsúná owó, o lè máa ronú bí o ti ma sá fún gbèsè. Ó dára láti yẹra fún gbèsè, ṣùgbọ́n bí Jésù ti sọ, óṣeéṣe kí o má jẹ gbèsè kankan pẹ̀lú àfikún ọ̀gọ̀rọ̀ owó ní ìpamọ́, síbẹ̀ ko bá araà rẹ nínú kòtò ìsúná. Ó yanilẹ́nu, àbí? Máa báwa ká lọ. 

Nínú ẹsẹ̀ Bíbélì tòní láti inú ìwé Mátíù, Jésù sọ wípé gbogbo wa laní ohun tàbí ẹni kan tó ń ṣàkóso wa. Ó wá fún wa ní àǹfààní láti yàn nínú ǹkan méjì tí a kò lérò: Ọlọ́run tàbí owó. Ọ̀pọ̀ nínú wa ni yóò lérò wípé Ó máa ní kí a yàn láàárín Ọlọ́run tàbí Sátánì. Ṣùgbọ́n Jésù fi yé wa wípé owóo wa ló ń bá ohun figa-gbága.

Ní pàtàkì jùlọ, ó wá ń bèrè wípé: Ṣé àwa ló ń ṣàkóso owó àbí owó ló ń ṣàkóso wa? 

Láìní irin-ìdáàbòbò tí ìsúná, ọ̀pọ̀ wa ni yóò bára wa láàrín ọ̀kan nínú kòtò méjì tí a ó dárúkọ. Nínúu ka yíwọ́ lọ sínú gegele ìnákúnàá tàbí ka lọ rọ́lu òkúta-àlà tí ìfowópamọ́. Ọ̀kan nííṣe pẹ̀lú ìfẹ́kúùfẹ́ tí kò ní ìjánu: ra, fi èyí tó dára jù tí tẹ́lẹ̀ rọ́pò, pẹ̀lú ṣíṣe èyí léraléra. Ìkejì nííṣe pẹ̀lú ẹ̀rù tí kò ní ìjánu: Tí ǹkan tí mo ní kò bá tó ńkọ́? Tàbí tí ǹkan bá ṣe mí?

Nínú àpèjúwe méjèèjì, owó ló jẹ́ olùṣàkóso. À ń lépa rẹ̀ ká ba le náa lójú-ẹsẹ̀. Tàbí lílépa rẹ̀ láti fi pamọ́ fún níná lọ́jọ́ iwájú.

A nílò irin-ìdáàbòbò tí ìsúná tí yóò mú Ọlọ́run jẹ́ Olùṣàkóso wa. Èyí là ń gbìyànjú láti sọ fún wa nínú Mátíù 6:33, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu nípa ìhà tó yẹ kí a kọ sí owó àti bí a ti ń lò ó. Ọ̀rọ̀ mélòó kan ni: "fi wíwá ìjọba rẹ̀ ṣe ìṣáájú." 

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ èyí tí ń fi ìjọba àwọn ẹlòmíràn ṣáájú. Tàbí, tí a bá máa yá ọ̀rọ̀ tí a lo lánàá: nínú ìjọba Ọlọ́run, ohun to dára fún àwọn ẹlòmíràn ní èyí tó dára jù lọ. Fífi ìsúná àwọn tó yí wa ká ṣáájú ni irin-ìdáàbòbò tí yóò pawámọ́ kúrò nínú kòtò ìnákúnàá àti ti ìfowópamọ́. 

Jẹ́kí fífi fúnni ṣáájú. Kí ìfowópamọ́ fún ọjọ́-iwájú ṣèkejì. Lẹ́yìn èyí, o lè wá ṣe ìtọ́jú araà rẹ. 

Lákọ̀ọ́kọ̀ fifún ni. Ìkejì fowó pamọ́. Fi èyí tó kù ṣe ìtọ́jú araà rẹ.

Ọ̀rọ̀ ìdùnnú nípa irin-ìdáàbòbò yí ni wípé: ìrọ̀rùn ló bá dé. Ní kété tí o bá ti mọ̀ ẹgbẹ́/ìgbìmọ̀ tàbí iṣẹ́ tí ọkàn rẹ fà sí, to sì ti ṣe ìlànà bí oó ti máa nawọ́ sí, irin-ìdáàbòbò yìí ni yóò mú kí ètò ìsúná rẹ máa lọ geere láì mú òógùn dání.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Guardrails: Avoiding Regrets In Your Life

A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìbá tí rí bí a bá ní iru irin í dáàbò bayi ninu àjọṣe wá, ìdọ́kòwò wá, àti isé wá? Báwo ni wọn yóò rí? Kí ni wọn ṣe lè pá wá mọ kúrò lọ́wọ́ ìkábàmọ̀? Fún ìwọ̀n ojo márùn-ún láti òní, ẹ jẹ ki a gbe bí a ṣe lè fi irú irin í dáàbò bayi sì ayé wa yẹ̀ wò.

More

A fé dúpé lówó North Point Ministries àti Andy Stanley fun ipèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.anthology.study/anthology-app