Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé RẹÀpẹrẹ

Bí kò ti sẹ́ni tó ma mọ̀ọ́mọ̀ ba ọkọ̀ọ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ jẹ́ ni kò ti sẹ́ni tí ó ma fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ bayé ara rẹ̀ jẹ́. Lójúu pópó, àwọn Irin-ìdáàbòbò wà láti dẹ́kun àwọn tó bá fẹ́ mórí wogbó láìrò tẹ́lẹ̀. Báwoni ìbáti dùntó tí irú Irin-ìdáàbòbò bá wà nínú ìgbésí-ayé wá bí ati se àpèjúwe yìí?
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àbámọ̀ wa tó lágbára jù ni aò bá ti yẹra fún tàbí dínkù ká ní a ní Irin-ìdáàbòbò tara ẹni fún owó wa, ìbárẹ́, bí a ti ń ṣe ìdájọ́, àti ẹ̀dùn-ọkàn.
Irin-ìdáàbòbò ara ẹni nííṣe pẹ̀lú gbèdéke ìhùwàsí wa àti ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí-okàn. Wọ́n jẹ́ ìlànà tí oti làálẹ̀ fún araà rẹ láti máa ta ẹ̀rí-ọkàn rẹ jí lóòrè-kóòrè. Àfi bíi Irin-ìdáàbòbò ojú pópó, àwọn ipele tí àtúnṣe ṣì ti rọrùn ni a máa ń gbé wọn sí. Kotó fi ọwọ́ọ̀ rẹ ba iṣẹ́-ààyò rẹ jẹ́, Irin-ìdáàbòbò kan yóò ti ta ọ́ lólobó wípé ewu ńbẹ lóko. Kí ó tó sọ ọ̀rọ̀ tí o kò ní lè kójẹ, Irin-ìdáàbòbò yìí ni yóò ti taọ́ lólobó láti ṣọ́ ọ̀rọ̀ enuù rẹ.
Bí a ti ńfi Irin-ìdáàbòbò tiwa sípò ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ń fún wa l'ámọ̀ràn wípé: "Ẹ máa ṣe àkíyèsí bí ẹ ti ńgbé ìgbésí-ayé yín—bí ọlọ́gbọ́n ẹ má sì ṣe bí òmùgọ . . ."
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ (bóyá ìwọ alára ti ní ìrírí rẹ̀) wípé o lè lọ sẹ́wọ̀n láì rú òfin. Ètò ìṣúná rẹ le dẹnukọlẹ̀ láì ná ìnákúnàá. O lè ba ìbárẹ́ jẹ́ láì ṣe ohunkóhun tó fara jọ ẹ̀ṣẹ̀.
A kò ṣe ìṣẹ̀dá Irin-ìdáàbòbò láti kọ́wa ni ǹkan tótọ́ àti ìdàkejì rẹ̀. Wọ́n wá níbẹ̀ láti kọ́ọ nípa ọgbọ́n.
Nítorí náà, ìbéèrè tí a máa múlò fún owó wa, ìbárẹ́, ìdájọ́, àti àwọn ẹ̀dùn-ọkàn nínú àwọn ọjọ́ mélòó kan wọ̀nyí: Ní ìrònú nípa àwọn ìrírí mi, àwọn ǹkan tí mò ń làkọjá lọ́wọ́lọ́wọ́, àti àwọn ìrètí ọjọ́-iwájú, kíni ǹkan tó mọ́gbọ́n dání láti ṣe?
Nínú ìgbéyàwó rẹ . . . nínú iṣẹ́-ààyò rẹ . . . nígbà tobá nílò láti ṣe ìpinnu nípa ibi tí o máa gbé tàbí bí o ti ma lo àkókò rẹ . . . kíni ǹkan to mọ́gbọ́n dání láti ṣe?
Báwoni ìbéèrè yìí ìbáti yí àwọn ǹkan toti yàn sẹ́yìn padà tàbi àwọn ipò àtijọ́ tí o fa àbámọ̀ fún ọ jùlọ? Ọ̀nà wo ni èyí ti lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Tóbá jẹ́ bèbè kòtò ni ìwọ ti ń rìn, àkókò tó láti lo Irin-ìdáàbòbò.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìbá tí rí bí a bá ní iru irin í dáàbò bayi ninu àjọṣe wá, ìdọ́kòwò wá, àti isé wá? Báwo ni wọn yóò rí? Kí ni wọn ṣe lè pá wá mọ kúrò lọ́wọ́ ìkábàmọ̀? Fún ìwọ̀n ojo márùn-ún láti òní, ẹ jẹ ki a gbe bí a ṣe lè fi irú irin í dáàbò bayi sì ayé wa yẹ̀ wò.
More