Kíni Ìdí Àjíǹde?Àpẹrẹ

Why Easter?

Ọjọ́ 5 nínú 5

Kìni a ní láti ṣe?

Májẹ̀mú Titun jẹ́ kí ó yé wa pé a ní láti ṣe nǹkan kan láti gba ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni. Èyí jẹ́ iṣẹ́ ìgbàgbọ́. Jòhánù kọ̀wé pé ‘Ọlọ̀run fẹ́ràn aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí Ó fí Ọmọ bíbí Rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, ki ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà Á gbọ̀ má bà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun’ (Jòhánù 3:16).

Fífi ọkàn tán níí ṣe pẹ̀lú iṣe ìgbàgbọ́, tí ó dá lórí gbogbo ohun tí a mọ̀ nípa Jésù. Kìí ṣe ìgbàgbọ́ tí ó fọ́jú. Ó jẹ́ fífi ìgbẹ́kẹ̀lé wá sínú Ẹnìkan. Ní àwọn ọ̀nà kan, ó dàbí ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ìyàwó tàbí ọkọ ìyàwó ń gbé nígbàtí wọ́n sọ̀ pé, ‘Emi yíò ṣé bẹ́ẹ̀’ ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn.

Ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbá gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí yàtọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n mo fẹ́ ṣe àpèjúwe ọ̀nà kan nínú èyítí ó lè fí gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí nísinsìnyí. A lè sọ ní ṣókí nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta tí ó rọrùn jọjọ:

'Mo Bẹ̀bẹ̀‘strong>

O ní láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún dáríjì gbogbo àìsedédé rẹ kí o ṣì yí padà kúrò nínú ohun gbogbo tí o mọ̀ pé kò tọ̀nà nínú ìgbésí ayé rẹ. Èyí ni ohun tí Bíbélì túmọ̀ sí ‘ìrònúpìwàdà.’

‘O Ṣeun’

À gbàgbọ́ pé Jésù kú fún wa lóríi àgbélébú. O ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ nítorípé Ó kú fún ọ àti fún ìpèsè ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ìdáríjì òmìnira, àti Ẹ̀mí Rẹ̀.

‘Jọ̀wọ́’

Ọlọ́run kò fi ipá mú wa láti tọ́ ìlànà Rẹ̀. O nílò láti gba ẹ̀bùn Rẹ̀ kí o sì pèé láti wá bá ọ gbé nínú rẹ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀.

Tí o bá fẹ́ ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó bá sì ṣe tán láti sọ àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí, lẹ́hìn náà èyí ni àdúrà tí ó rọrùn tí yíò sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìbásepọ̀ yẹn:

Oluwa Jesu Kristi,

Mo bẹ̀bẹ̀ fún àwọn àṣìṣe tí mo ti ṣe ní ìgbésí ayé mi ( lo àkókò dí ẹ̀ láti tọrọ fún ìdáríjì Rẹ̀ pàápàá jùlọ fún ohunkohun tí ó jẹ́ ẹ̀rí-ọkàn fún ọ). Jọ̀wọ́ dáríjì mí. Nísinsìnyí mo yí padà kúrò nínú gbogbo àṣìṣe mi.

O ṣeun pé O kú lóríi àgbélébùú fún mi kí á lè dáríjì mí àti sọ mí di òmìnira.

O ṣeun pé O fún mi ní ìdáríjì àti ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Rẹ. Mo gba ẹ̀bùn yẹn nísinsìnyí.

Jọ̀wọ́, jẹ́kí Ẹ̀mí Mímọ́ wá sínú ayé mí kì ó sì má bá mi gbé títí láí.

O ṣeun, Olúwa Jésù. Àmín.

Idagbasoke   Bọtini: ọjọ_5

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Why Easter?

Kíni ohun tó ṣe pàtàkì gan nípa àkókò Àjíǹde? Kíló ṣe tí gbogbo ojú fi wà ara ẹnìkan tí a bí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Kílódé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi n ní ìtara nítorí Jésù? Kíni ìdí tí a fi ní lò Rẹ̀? Kílódé tó fi wá? Kílódé tó fi kú? Kíni ìdí tí ó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni gbèrò láti wádìí? Nínú ètò ìlànà ọlọ́jọ́ 5, Nicky Gumbel pín àwọn ìdáhùn tó múná d'óko sí àwọn ìbéèrè náà.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Alpha àti Nicky Gumbel tí wọ́n pèsè ètò ìlànà yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lo sí: https://alpha.org/