Kíni Ìdí Àjíǹde?Àpẹrẹ
Òmìnira lọ́wọ́ kíni?
Jésù san owó ìràpadà pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lórí àgbélébùú, kí Ó lè dá wa nídè.
Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi
Yálà a nímọ̀lára pé a jẹ̀bi tàbí a kò jẹ̀bi, gbogbo wa la jẹ̀bi níwájú Ọlọ́run nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà tí a ti rú òfin rẹ̀ nínú ìrònú, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó bá ṣe ìwà ọ̀daràn ṣe máa ń jìyà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó bá rú òfin Ọlọ́run ṣe máa ń jìyà. 'Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀‘ (Róòmù 6:23).
Àbájáde àwọn ohun tí a bá ṣe tí kò dára ni ikú ti ẹ̀mí—èyí ni ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run títí láé. Gbogbo wa ló yẹ ká jẹ irú ìyà yí. Ní orí àgbélébùú, Jésù gba ìyà náà dípò wa kí a lè rí ìdáríjì gbà pátápátá, kí a sì lè mú ẹ̀bi wa kúrò.
Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìkúndùn òdì
Jésù sọ pé "olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀" (Jòhánù 8:34). Jésù kú ká lè tú wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ìsọdẹrú yìí. Ní orí àgbélébùú, agbára ìkúndùn òdì já dànù. Bótilẹ̀jẹ́pé a ṣì lè máa ṣubú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, agbára ìkùndùn òdì ti di jíjá nígbà tí Jésù tú wa sílẹ̀.
Òmìnira kuro lọwọ́ ìbẹ̀rù
Jésù wá kí Ó lè "fi ikú Rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára lórí ikú run, ìyẹn èṣù, kí Ó sì dá gbogbo àwọn tí ìbẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn sílẹ̀"(Hébérù 2:14-15). A ò nílò láti bẹ̀rù ikú mọ́.
Ikú kì í ṣe òpin fún àwọn tí Jésù ti dá sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹnu ọ̀nà tó lọ sí ọ̀run, níbi tí a ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí Jésù dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú, Ó tún dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìbẹ̀rù mìíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni ohun tó ṣe pàtàkì gan nípa àkókò Àjíǹde? Kíló ṣe tí gbogbo ojú fi wà ara ẹnìkan tí a bí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Kílódé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi n ní ìtara nítorí Jésù? Kíni ìdí tí a fi ní lò Rẹ̀? Kílódé tó fi wá? Kílódé tó fi kú? Kíni ìdí tí ó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni gbèrò láti wádìí? Nínú ètò ìlànà ọlọ́jọ́ 5, Nicky Gumbel pín àwọn ìdáhùn tó múná d'óko sí àwọn ìbéèrè náà.
More