Kíni Ìdí Àjíǹde?Àpẹrẹ

Why Easter?

Ọjọ́ 4 nínú 5

Òmìnira fún kínni?  

Jésù kò sí láyé mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n kò fi wá sílẹ̀. Ó rán È̩mí Mímọ́ rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wa. Nígbà tí È̩mí rẹ̀ bá wá ń gbé inú wa, á fún wa ní òmìnira tuntun.

Òmìnira láti mọ Ọlọ́run

Àwọn ohun tí à ń ṣe lódì máa ń fa ìdènà láàrin àwa àti Ọlọ́run: ‘ṣùgbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin àti Ọlọrun yín’ (Aisaya 59:2). Nígbà tí Jésù kú lórí àgbélébùú, ó mú ìdènà tó wà láarin wa àti Ọlọ́run kúrò. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti jẹ́ k'ó ṣeéṣe fún wa láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹlẹ́dà wà. A ti di ọmọ rẹ́ l'ókúnrin àti l'óbìnrin. È̩mí náa ńfi ọ̀kàn wa balẹ̀ lórí ìbaṣepọ̀ yí, ó sì ń ràn wa lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run sí i. Ó ń ràn wa lọ́wọ́ láti gbàdúrà ó sì ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Bíbélì) yé wa..

Òmìnira láti fẹ́ràn

‘A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọ́run ni ó kọ́ fẹ́ràn wa’ (1 Johanu 4:19). Bí a ṣe ń wo àgbélébùú, ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa á máa yé wa. Nígbà tí È̩mí Ọlọ́run bá wá ń gbé nnú wa, a ó ní ìrírí ìfẹ́ yìí. Bí a ti ń ṣe èyí, a máa ń gba ẹ̀bùn ìfẹ́ tuntun fún Ọlọ́run àti fún gbogbo ènìyàn. A tú wa sílẹ̀ láti gbé ayé ìfẹ́ - ayé tí ó dálé fífẹ́ àti sísin Jésù àti àwọn ẹlòmíràn, dípò fífẹ́ ara wa nìkan..

Òmìnira láti yípadà

Ìgbà míràn àwọn ènìyàn máa ń sọ pé, 'Bí o ṣe rí lo rí. Oò lè yí ẹlẹ́dà rẹ padà.' Ìròyìn ayọ̀ ni pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ È̩mí Mímọ́, a lè yií padà. È̩mí Mímọ́ ń fún wa ní òmìnira láti máa gbé ìgbésí ayé tó ti ń wùn wá láti ìsàlẹ̀ ọkán wa. Pọ́ọ̀lù Ẹni Mímọ́ sọ fún wa pé èso ti Ẹ̀mí ni 'ìfẹ́, ayọ̀, alàafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́, ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìsẹ́ra-ẹni' (Galatia 5: 22-23). Nígbà tí a bá pé È̩mí Ọlọ́run wípé k'ó máa wá gbé nínú wa, àwọn àbùdá ìyanu yìí á bẹ̀rẹ̀ sií dàgbà nínú ayé wa.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Why Easter?

Kíni ohun tó ṣe pàtàkì gan nípa àkókò Àjíǹde? Kíló ṣe tí gbogbo ojú fi wà ara ẹnìkan tí a bí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Kílódé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi n ní ìtara nítorí Jésù? Kíni ìdí tí a fi ní lò Rẹ̀? Kílódé tó fi wá? Kílódé tó fi kú? Kíni ìdí tí ó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni gbèrò láti wádìí? Nínú ètò ìlànà ọlọ́jọ́ 5, Nicky Gumbel pín àwọn ìdáhùn tó múná d'óko sí àwọn ìbéèrè náà.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Alpha àti Nicky Gumbel tí wọ́n pèsè ètò ìlànà yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lo sí: https://alpha.org/