Kíni Ìdí Àjíǹde?Àpẹrẹ
Kí nìdí tó fi wá sáyé, kí sì nìdí tó fi kú?
Jésù nìkan ni ẹni tó yàn láti di bí bí, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn dí ẹ̀ tó yàn láti kú. Ó sọ pé ìdí tí Ó ún fi wá ni pé kí Ó kú fún wa. Ó wá láti 'fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.' (Máàkù 10:45).
Jésù sọ pé Òun kú 'fún' wa. Ọ̀rọ̀ náà 'fún' túmọ̀ sí 'dípò.' Ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì fẹ́ ká jìyà fún gbogbo àṣìṣe wa. Nígbà tó wà lórí àgbélébùú, ohun tó ń sọ ni pé, 'Èmi yóò gba gbogbo àwọn ǹkan yẹn sórí ara mi'. Ó ṣe é fún ọ, Ó sì ṣe é fún mi. Tí ó bá ṣe pé èmi tàbí ìwọ nìkan la wà láyé yìí, Yóò ṣe é fún wa síbẹ̀. Pọ́ọ̀lù ẹni mímọ́ nì kọ̀wé nípa 'Ọmọ Ọlọ́run, tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi' (Gálátíà 2:20). Ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà.
Ọ̀rọ̀ náà "ìràpadà" wá látinú oko-òwò ẹrú. Ẹni rere lè ra ẹrú kan, kó sì dá a sílẹ̀ lómìnira, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ san owó ìràpadà. Jésù fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ san ìràpadà lórí àgbélébùú láti dá wa nídè.
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni ohun tó ṣe pàtàkì gan nípa àkókò Àjíǹde? Kíló ṣe tí gbogbo ojú fi wà ara ẹnìkan tí a bí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Kílódé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi n ní ìtara nítorí Jésù? Kíni ìdí tí a fi ní lò Rẹ̀? Kílódé tó fi wá? Kílódé tó fi kú? Kíni ìdí tí ó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni gbèrò láti wádìí? Nínú ètò ìlànà ọlọ́jọ́ 5, Nicky Gumbel pín àwọn ìdáhùn tó múná d'óko sí àwọn ìbéèrè náà.
More