Iṣé Ìrànṣe ÌtayọÀpẹrẹ
Àìbìkítà: Ìkùnà Ìfẹ́
Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù pé èwo ni àṣẹ tó tóbi jù lọ, ó dáhùn pé: "‘Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ... àti... Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ." Bí á ṣe rí i l'ọjọ́ àná, iṣẹ́ tí ó tayọ ni ọ̀nà kan tí á fi ń pa àṣẹ tí jésù pa pé kí á nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mọ́ nípa ṣíṣàfihàn àwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ fún àwọn tó yí wa ká. Bí a ó rí i lónìí,ó tún pọn dandan láti jẹ́ ẹni tó dáńgájíá láti lè pa àṣẹ kejì mọ́ nínú iṣẹ́ wa.
Gẹ́gẹ́ Bí Kristẹni, a ò lè sọ pé a ń wá bí á ṣe lè fẹ́ràn ọmọnìkejì wa bí ara wa kí a sì máa ṣe iṣẹ́ wa lọ́nà tí kò dára. Ronú nípa àpẹẹrẹ oníṣègùn kan tó jẹ́ Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé dókítà yẹn lè gbàdúrà pẹ̀lú àwọn aláìsàn rẹ̀, tí ó ń wàásù ìhìn rere fáwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, tí ó sì máa ń fowó ṣètọrẹ fún ìjọ rẹ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ó jẹ́ dókítà tó dáńgájíá. Tó bá jẹ́ pé oníṣègùn tí kò já fáfá ni, ẹ̀mí àwọn aláìsàn rẹ̀ lè wà nínú ewu. Ojúṣe àkọ́kọ́ tí dókítà ní nínú iṣẹ́ rẹ̀ yẹ kí ó jẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó tayọ jùlọ—ó gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ó bá lè ṣe fún àwọn aláìsàn rẹ̀, fífún wọn ní àbójútó kan náà tí yóò retí fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀.
Nní báyìí, fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wa, ọ̀nà tí á gbà ń ṣe iṣẹ́ wa kò ní túmọ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìyè àti ikú. Àmọ́ gbogbo wa la láǹfààní láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí á fẹ́ràn ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí ara wa nípa kí a yan láti ṣe iṣẹ́ tó dára gan-an ati pe kí a kọja awọn ipele tí o kere julọ ti a beere ninu awọn iṣẹ wa. Mo fẹ́ràn ohun tí Matt Perman sọ lórí àkòrí yìí: “Iṣẹ́ àṣekúdórógbó dà bí ìwà ìbàjẹ́ nítorí pé ó ń mú kí ìgbésí ayé nira fún àwọn èèyàn—bí ìwà ìbàjẹ́. Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn tó ń fi iṣẹ́ wọ́lẹ̀. Iṣẹ́ tí ó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní la gbọ́dọ̀ ṣe nípa ṣíṣe ohun tó ju agbára wa lọ dípò tí a bá ṣe ìwọ̀nba ohun tí a nílò. Àṣeyọrí nínú iṣẹ́ wa jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi ń fi ìwà ọ̀làwọ́ àti ìfẹ́ hàn, àti pé iṣẹ́ tí kò dára jẹ́ ọ̀nà kan láti fi hàn pé èèyàn jẹ́ òǹrorò àti onímọtara-ẹni-nìkan. Iṣẹ́ tí ò dáa kì í wulẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí kò dáa nìkan; iṣẹ́ àìsí ìfẹ́ ni.”
Gẹ́gẹ́ Bí Kristẹni, a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ tó kéré jù lọ nínú iṣẹ́ wa láti gba owó oṣù. Bí a bá gbàgbọ́ wípé iṣẹ́ wa jẹ́ ìpè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a ó ṣe é “tọkàntọkàn fún Olúwa (Colossians 3:23),” nípa wíwá ògo fún ọlọ́run àti nípa kí á fẹ́ràn ọmọnìkejì wa dáadáa nípa jíjẹ́ àwọn dókítà, àwọn oníṣòwò, àwọn olùkọ́, àwọn ayàwòrán, àwọn káfíńtà, àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ tó pọkàn pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì tayọ, tí a lè di. Àṣeyọrí nínú iṣẹ́ wa kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀nà láti rí èrè ti ara ẹni. Àṣeyọrí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nínú iṣẹ́ wa. Ẹ jẹ́ kí òtítọ́ yìí fún yín níṣìírí láti pọkàn pọ̀ sórí lílóye iṣẹ́ ọwọ́ yín dáadáa, dídi ẹ̀dà ara rẹ tí ó dára ọ̀tọ̀ jù lọ fún ògo Ọlọ́run àti ire ọmọnìkejì wa!
Tí o bá gbádùn ètò ìwé kíkà yìí, ẹ ó fẹ́ràn ìfọkànsìn mi lọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ so ìhìn rere pọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ. Forúkọ sílẹ̀ níbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdí tí ó l'ẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni ó wà tí a fi gbọ́dọ̀ lépa ìtayọ ní ẹnú iṣẹ́ wa: Ìtayọ ń mú iṣẹ́ wa gbòòrò sí, ó ń jẹ́ kí a ní ipa rere, ó sì lè y'ọrí sí àǹfààní láti tan ìhìnrere ká. Ṣùgbọ́n bí a ó ti rí i nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, a ní láti lépa ìtayọ fún ìdì pàtàkì kan—nítorí pé ìtayọ ni ọ̀nà tí a fi lè fi àbùdá Ọlọ́run hàn, kí a sì ní ìfẹ́ àti kí a ṣiṣẹ́ sìn ọmọlàkejì wa bíi ara wa nípa iṣẹ́ tí a yàn láàyò.
More