Iṣé Ìrànṣe ÌtayọÀpẹrẹ
Kéde Àwọn Ìtayọlọ́lá Ọlọ́run
Ohun tí iṣẹ́ wa wà fún kò yàtọ̀ sí ohun tí ìgbésí ayé wa wà fún, ìyẹn ni pé ká máa fi ògo fún ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí á bá ń ṣe (1 Kọ́ríńtì 10:31)."Yììwànlógo" jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a máa ń sọ káàkiri tí ó sì máa ń ṣòro láti ṣàpèjúwe. Bí John Piper ṣe sọ, fífi ògo fún Ọlọ́run kò ju pé kí a “fi títóbi lọ́ba re hàn” tàbí kí a sọ irú ẹni tí ó jẹ́ fún áwọn ẹlòmíì.
Nítorí náà, bí ète iṣẹ́ wa bá jẹ́ láti fi ìwà Olúwa hàn sí ayé. Àwọn ànímọ́ wo gan - an ló ní? Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá rẹ̀ tó dáńgájíá èyí lè jẹ́ èyí tó hàn kedere jù lọ fún wa. O ò lè wo àfonífojì Grand Canyon kí ó má sì máa ṣe kàyéfì nípa iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe. O ò lè lọ sí ọgbà ẹranko láì mọrírì agbára ìṣẹ̀dá tí Ẹlẹ́dàá ní. O ò sì lè mú ọwọ́ ọmọ kan, kí ó máà jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu láti rí bí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tó láti dá ìwàláàye. Bí a ti rí i nínú àyọkà ti àná, Ìwà Ọlọ́run tó ga jù lọ tún tàn yòò nínú ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àwọn alákòókò rẹ̀ tí wọ́n ń ṣe kàyéfì pé "ó ti ṣe ohun gbogbo dáadáa". Ọlọ́run tó ga jù lọ là ń sìn. Ọlọ́run pípé. “Ó dára gan-an" jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò bóde mu láti ṣàpèjúwe Ọlọ́run àgbáyé. Àmọ́ ohun tó sún mọ́ wa jù lọ ni pé àwa èèyàn lásánlàsàn lè ní ìrètí pé a óò lóye rẹ̀, a ó sì rí i gbà.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, a ti pè wá láti máa gbé àwòrán Baba wa tí kò lẹ́gbẹ́ wọ̀. Nínú Ìwé Éfésù 5:1, Pọ́ọ̀lù fún Ìjọ ní Ìtọ́ni "Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n". Nígbà tí Andreas Köstenberger tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ń se àlàyé lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ó sọ pé: "Báwo ló ṣe yẹ kí a fi hàn pé a mọrírì oore Ọlọ́run?" Ní ṣòkí, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti fara wé jáde lọ, kí a sì fi ṣe àwòkọ́ṣe. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí Ọlọ́run ti rà padà, a gbọ́dọ̀ sapá láti dà bí Ọlọ́run. Ó dà bíi pé èyí ní í ṣe pẹ̀lú kí a máa sapá ọ̀nà tó dára jù lọ.” John Piper sọ ọ́ báyìí: “Ọlọ́run dá emi—àti ìwọ—láti gbé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn kan ṣoṣo, tí ó gba gbogbo nǹkan, tí ó yí gbogbo nǹkan padà—ìyẹn ni, ìfẹ́ láti máa yin Ọlọ́run lógo, nípa níní inú dídùn sí jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ẹni gíga jù lọ àti nípa fífi ànímọ́ rẹ̀ tí kò láfiwé hàn nínú gbogbo apá ìgbésí ayé.”
Ní àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn, a máa ń fi ògo fún Ọlọ́run nígbà tí á bá fara wé ìwà rẹ̀ tí ó dára jù lọ àti nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn” (1 Pétérù 2:9).Inú òkùnkùn biribiri là ń gbé nínú ayé kan tó ń wá ohun kan tó dára gan-an tó sì jẹ́ òótọ́ lójú méjèèjì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò sí àyíká ìgbésí ayé tí ó ní ipa tó ju èyí lọ fún wa láti tan ìmọ́lẹ̀ Kristi ju nínú iṣẹ́ tí á yàn. Nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú títayọ, àǹfààní ńlá la ní láti máa yin Ọlọ́run lógo áti lát máa polongo àwọn ànímọ́ rẹ̀ fún gbogbo ayé tó yí wa ká. Jáde lọ ṣe iṣẹ́ rẹ lọ́nà tí ó dára jùlọ lónìí!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdí tí ó l'ẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni ó wà tí a fi gbọ́dọ̀ lépa ìtayọ ní ẹnú iṣẹ́ wa: Ìtayọ ń mú iṣẹ́ wa gbòòrò sí, ó ń jẹ́ kí a ní ipa rere, ó sì lè y'ọrí sí àǹfààní láti tan ìhìnrere ká. Ṣùgbọ́n bí a ó ti rí i nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, a ní láti lépa ìtayọ fún ìdì pàtàkì kan—nítorí pé ìtayọ ni ọ̀nà tí a fi lè fi àbùdá Ọlọ́run hàn, kí a sì ní ìfẹ́ àti kí a ṣiṣẹ́ sìn ọmọlàkejì wa bíi ara wa nípa iṣẹ́ tí a yàn láàyò.
More