Iṣé Ìrànṣe ÌtayọÀpẹrẹ

The Ministry Of Excellence

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ìtayọ nínú Ohun Gbogbo

Ọ̀kan nínú àwọn àkàwé Jésù tí mo fẹ́ràn jù wà nínú Máàkú 7:37 tí ó sọ wípé “Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi rékọjá, wọ́n wípé. 'O [Jésù] ṣe ohun gbogbo dáradára.’” Gẹ́gẹ́ bí atẹ̀lé Jésù, ó yẹ kí àyọkà yìí mú wa t'ẹsẹ̀ dúró díẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó ń wá láti kọ́ ìṣe Jésù ní gbogbo ọ̀nà, ǹjẹ́ a lè sọ wípé à ń ṣe ohun gbogbo dáradára? Ǹjẹ́ a lè sọ wípé à ń ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ìtayọ ní ẹnu iṣẹ́ àti ní inú ilé?

Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé gbogbo wa ni a ti kùnà ìlànà Jésù tí ó tayọ. Èrò mi ni wípé èyí rí bẹ́ẹ̀ lónìí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Kíni ìdí? Nítorí pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a gbàgbọ́ nínú irọ́ pé a ní láti ṣe ohun gbogbo, jẹ́ ohun gbogbo, kí a sì ní ohun gbogbo. A ti fi ara jìn jú, ohun gbogbo pakasọ mọ́ wa lọ́wọ́, ó sì t'ojú sú wa, à kò ní àṣeyọrí tààrà nínú ohunkóhun nítorí pé a kò mọ ìyàtọ́ láàrin ohun tí ó ṣe pàtàkì àti èyí tí kò ṣe pàtàkì nínú iṣe wa àtí nínú ilé wa. Èyí ni okùnfà ìmẹ́ẹ́rí, kìí ṣe ìtayọ, mo sì lè sọ wípé ìṣòro yìí ti di tọ́ọ́rọ́ fọ́n k'álé nínú ìjọ lónìí.

Kíni ìdí tí eléyìí ṣe gbọ́dọ̀ ká wa lárà? Nítorípé ohunkóhun tí ó bá kéré sí ìtayọ kùnà ìlànà tí a pe àwa Krìstíẹ́nì sí. Nínú 1Kòríntì 10:31, Pọ́ọ̀lú kọ ìwé pé, “Nítorínáà bí ẹ̀yin bá ń jẹ, tàbí bí ẹ̀yin bá ń mu, tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn fún ògo Ọlọ́run.” Olóògbé olúsọ́-àgùntàn àti ọ̀mọ̀wé Jákọ́bú Kennedy maá ń ṣe àtúnsọ ẹsẹ yìí, ní pípe àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ sí “ìtayọ̀ nínú ohun gbogbo àti ṣíṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” Èyí ni ìlànà tí a pè wá sí.

Àìmọye ìdì pàtàkì ni ó wà tí a fi gbọ́dọ̀ lépa ìtayọ nínú ohun gbogbo, pàápàá jùlọ nínú iṣẹ́ tí a yàn láàyò. Ìtayọ nínú iṣẹ́ wa, maá ń mú iṣẹ́ wa gbòòrò sí í, ó maá ń mú wa jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà ní ayé, ó maá ń mú wa ní ipa, ó sì lè fún wa ní àǹfààní láti tan ìhìnrere ká. Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ohun rere yìí tí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kókó ìwúrí fún wa bí a ṣe ń lépa ìtayọ nínú iṣẹ́ wa àti àwọn ipò míràn tí Ọlọ́run pè wá sí ní ayé. À ń lépa ìtayọ fún ìdí pàtàkì míràn tí ó ga jù—nítorí pé ìtayọ ni ọ̀nà tí a fi lè fi àbùdá Krístì hàn, kí a sì ní ìfẹ́ àti kí a ṣiṣẹ́ sìn ọmọlàkejì wa bíi ara wa. L'ẹ́nu kan, ìtayọ ní iṣẹ́ ìsìn wa ojoojúmọ́. Bí a ó ṣe máa rí i ní àwọn ọjọ́ méjì tí ó kù, nípa iṣe ìsìn ìtayọ ní a fi ń fí ògo fún Ọlọ́run tí a sí ń fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn nípa iṣẹ́ wa.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

The Ministry Of Excellence

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdí tí ó l'ẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni ó wà tí a fi gbọ́dọ̀ lépa ìtayọ ní ẹnú iṣẹ́ wa: Ìtayọ ń mú iṣẹ́ wa gbòòrò sí, ó ń jẹ́ kí a ní ipa rere, ó sì lè y'ọrí sí àǹfààní láti tan ìhìnrere ká. Ṣùgbọ́n bí a ó ti rí i nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, a ní láti lépa ìtayọ fún ìdì pàtàkì kan—nítorí pé ìtayọ ni ọ̀nà tí a fi lè fi àbùdá Ọlọ́run hàn, kí a sì ní ìfẹ́ àti kí a ṣiṣẹ́ sìn ọmọlàkejì wa bíi ara wa nípa iṣẹ́ tí a yàn láàyò.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jordan Raynor fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: http://www.jordanraynor.com/excellence