ỌLỌ́RUN + ÌLÉPA: Ọ̀nà Láti Gbé Ìlépa Kalẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí KristẹniÀpẹrẹ
ỌJỌ́ KẸTA: Ki ní àwọn ìlépa tí ó ní àtìlẹyìn ìgbàgbọ́ fara jọ?
Kí ni àwọn ìlépa tí Olórun darí dà bí? Ṣe o lè ní ìlépa tí kò ṣe tààrà sí iṣẹ́ ìránṣẹ́- bíi dídín ọ̀rá-ara kù tàbí pipàdà sí ilé-ìwé? Àbí, ṣe gbogbo ìlépa rẹ ló gbọ́dọ̀ jọ mọ́ "gbígbàdúrà síi," "lílọ sí ìrìn-àjò ìjíhìnrere," àti "lílọ sí ilé ìjọsìn"?
Àwọn ìlépa kan àti àwọn ìṣe kan tí wà tí a ṣètò sílẹ̀ fún wa nínú ìwé mímó, èyí tó tún rán wá lówó: kà Bíbélì rè (Orin Dáfídì 119:9), lo àkókò nínú ádùrá (Tẹsalóníkà Kínní 5:17-18), wà pèlú àwon onígbàgbó mìíràn (Hébérù 10:25), àti ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rè (Orin Dáfídì 96:3). Olórun fé àwọn ohun wọnyí fún wa láti mú wa sún mọ ara Rẹ̀—láti mú wa so èso àti láti jẹ́ olódodo. Èyí kìí ṣe ìwé tí à ń buwọ́ lù láti tẹ̀lé, káká bẹẹ àbájáde ọkàn tí a tí yí padà nípa oore ọ̀fẹ́ Olórun. A sún wa láti ṣe àwọn ohun wọnyìí nítorí O fẹ́ràn wa gidi gan.
Ṣùgbón kíni nípa ìyókù ayé? Ọlọrun fẹ ki a ṣe ohun gbogbo fun ògo Rẹ̀ (1 Korinti 10:31) - awọn ìlépa nlá ti O ni fún wa ati ohun ti o dàbí ẹni pé wọn kò wuni lórí. Bóyá o n ṣe ìṣòwò kan, parí èkó goyè, o ń tó ọmọ lówó, ṣiṣe awọn ìpinnu ìnáwó ọlógbọn, bójútó ara rẹ̀, tàbí pàápàá fi gbogbo àwọn ìfoso rẹ pamọ́ (ìfoso ti èmí? Béèni!), Ti a ba ṣe àwọn nǹkan wọnyìí pẹ̀lú ète lati wu Olôrun, o lè lo wọn lati jẹ ìmólè fún Un. Kò túmọ si pé a ni lati wa ni pípé nínú àwọn ìwà wa nínú àwọn nǹkan wonyen tabi ìlọsíwájú wa, o kan ni látí jẹ́ olóòótọ.
Nígbà tí a bá ṣe fún ògo Rè, àwọn ènìyàn rí ohun tó yàtọ nínú wa. Wọ́n ní ìyàlẹ́nu ibi tí ìrètí wa ti ń wá àti, nípa ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a máa ní àǹfààní láti ṣe àjọpín Orísun náà. Níhìn, ṣe gbogbo ìlépa rè ní láti jé nípa missions àti ṣinṣin sóòsì rè? Níbikíbi tí Ọlọ́run bá ti fi ọ́ sí, máa tàn níbi tí a fi ọ́ sọlẹ̀ sí. Súfèé bí o ti ń ṣiṣẹ́, àti pé èyí tó ṣe ìwúlò kan pàtó máa dí èyí tó nítumò!
Gbàdúrà pèlú mi: Bàbá, É ṣeun fún bí ẹ ti fẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níhìn ibi tí mo wa. Ẹ ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ lórí àwọn ohun tí É tí gbéka iwájú mi pèlú ojú témi, ní rírí won gégé bí àwọn ìlépa tí Ọlọ́run darí, kò sí bí iṣẹ́ tó ka iwájú mi ti rí. É ràn mí lówó láti jé kí gbogbo ohun tí ń mo se dà lé mi lórí—pàápàá àwọn ìgbà tí mo bá bàjẹ́ tàbí kùnà. É jé kí oore ọ̀fẹ́ jẹ́ àsíá mi bí mo ṣe ń tẹ̀síwájú lórí àwọn ìlépa mi, ní mímò pé kìí ṣe nípa ijépípé, o jé nípa Yín— alásépé àti olùjépípé ìgbàgbọ́ wa. Ní orúkọ Jésù. Àmín!
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o dára láti ní ìlépa gégé bí Kristẹni? Báwo ní o ṣe lẹ̀ mọ̀ tí ìlépa rẹ bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí ara rẹ? Àti wípé báwo ni ìlépa Kristẹni ṣe rí ní pàtó? Nínú ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, o máa ṣàwárí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti rí ìtọ́sọ́nà lórí gbígbé ìlépa tó kún fún ore-ọ̀fẹ́ kalẹ̀!
More