Fún Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Ìtunmọ̀Àpẹrẹ
Yíyàn Láti Tẹ̀lé Ìtumọ̀ Tí Ọlọ́run Fún Iṣẹ́
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwa Kristẹni máa ń lérò wípé àwọn iṣẹ́ tó jẹ Ọlọ́run lógún ni ti olùṣọ́-àgùntàn, ajínhìn-rere, àti àwọn òní ìtọrẹ-àánú. Ewu tó wà níbẹ̀ ni wípé a máa bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àwọn iṣẹ́ tó kù bí èyí tí kò ní ìtumọ̀, èyí sì lè mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá ìhà àti ìwúrí wa. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, gbogbo iṣẹ́ ló jẹ Ọlọ́run lógún. Ọlọ́run fẹ́ kí a sọ wọ́pọ̀ pẹ̀lú Òhun nínú gbogbo iṣẹ́ wa, láti sin àwọn mìíràn fún àwọn ètò Ọlọ́run láti di mímú ṣe.
Jósẹ́fù ní òye nípa ǹkan wọ̀nyí, kódà nínú ìdánwò tó nira jù. Jósẹ́fù kò ní ìhùwàsí búburú, pàápàá pẹ̀lú bí ìrírí rẹ̀ ṣe ń takókó síi. Kò ṣe iṣẹ́ àkókò náà pẹ̀lú ìmẹ́lẹ́ pẹ̀lú ìtọrọ gáfárà wípé èyí kí ìṣe ohun tí a pèé fún. Jósẹ́fù mọ ẹni tí òhun ń ṣiṣẹ́ fún ní tòótọ́ – Ọlọ́run. Fún ìdí èyí, Jẹ́nẹ́sísì 39 sọ fúnwa wípé “Ọlọ́run wà pẹ̀lú Jósẹ́fù” ní ìgbà mẹ́rin (Jẹ́nẹ́sísì Gen 39:2, 3, 21, 23). Nígbà tí aya Pọtifari kò dẹkùn láti máa tọ Jósẹ́fù lọ, ó ní “ọ̀gá mi kò bìkítà fún ohun kan nínú ilée rẹ̀. […] Báwo ni … èmi yóò ti ṣẹ̀ s'Ọ́lọ́run?” Jósẹ́fù mọ̀ dájú wípé àti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àṣeyọrí òhun ti wá àti wípé ohun nílò láti buọlá fún Ọlọ́run.
Pẹ̀lú bí Jósẹ́fù ti yàn láti ṣe ohun tó tọ́, wọ́n parọ́ mọọ, le kúrò lẹ́nu iṣẹ́, a sì sọọ́ sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n. Pẹ̀lú gbogbo ìtakò to ni ìrírí rẹ̀, Jósẹ́fù kò dẹkùn láti máa buọlá fún Ọlọ́run àti láti ran àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kan si, Ọlọ́run mú kó rí ojú-rere gbà lọ́dọ̀ adarí ọgbà-ẹ̀wọ̀n.
Wọn yóò fi ìlọ̀kúlọ̀ lọ̀wá ni ibiṣẹ́, bíi Jósẹ́fù. A ní láti ṣọ́ra kí ìhùwàsí búburú sí iṣẹ́ má sọlẹ̀ lọ́kàn wa nígbà tí ǹkan kò bá lọ bótiyẹ́. Jésù fi yé wa wípé, “Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé. Ṣùgbọ́n ẹ ṣe ara gírí! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33). A ní láti máa gbé nínú Kristi ni gbogbo ipò tí a bá bára wa, iṣẹ́ ọwọ́ wa yóò sì máa pọ̀si (Jòhánù 15:5).
Kíni o lè ṣe láti máa ní ìrísí iṣẹ́ẹ̀ rẹ bí Ọlọ́run ti ríi?
Àdúrà
Ọlọ́run Baba, mo dúpẹ́ fún iṣẹ́ tí o fi fún mi. O ṣeun tí o mú mi ṣe àṣeyọrí. Ràn mí lọ́wọ́ láti máa gbé nínú rẹ kí mba lè máa ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ lọ́nà tó tayọ ní ọjọ́ gbogbo, pàápàá ní àkókò tí ǹkan kò lọ bí mo ti fẹ́. Ràn mí lọ́wọ́ láti fi Jésù ṣe àfojúsùn mi ní gbogbo ìgbà. Lórúkọ Jésù. Àmín.
Láti ṣe àwárí síwájú síi
Ṣe àwárí bí a tií mọ ètò Ọlọ́run fún iṣẹ́ wa. Wo àwòrán yìí pẹ̀lú Bonnie Wurzbacher , SVP àtijọ́, ní ilé-iṣẹ́ Coca-Cola.
Nípa Ìpèsè yìí
Púpọ̀ nínú wa ni yíò lo bi ìdajì aiyé wa lágbà lẹ́nu iṣẹ́. Afẹ́ mọ̀ wípé iṣẹ́ wa ní ìtunmọ́ pé iṣẹ́ wa ṣẹ kókó. Ṣùgbọ́n áapon, ìpèníjà àti ìpọ́njú le mú kí a rí isẹ́ bi ohun líle tí aní láti là kọjá. Ètò yí yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ agbára tí o ní láti yan ìtunmọ̀ rere tí ó gbilẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ fún iṣẹ́ re
More