Fún Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Ìtunmọ̀Àpẹrẹ

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ní Ibiṣẹ́ Ní Gbogbo Ìgbà
Ẹni tí à ń ṣíṣe fún ṣe kókó àti wípé ó nííṣe pẹ̀lú tí iṣẹ́ yóò ní sí wa. Tí a bá bọlá fún àwọn alábàáṣiṣẹ́ wa tí a sì ní èròńgbà rere fún ilé-iṣẹ́ náà, yóò rọrùn fúnwa láti sa gbogbo ipá wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ti wùwà sì wa lọ́nà àìtọ́, tàbí ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan, yóò rọrùn fún ìrẹ̀wẹ̀sì láti wọlé wá, kó sú wa àti láti bẹ̀rẹ̀ ìkùnsínú. Ìrísí wa nípa àwọn ẹlòmíràn ní agbára láti yí ìhà tí à ń kọ sí iṣẹ́ padà.
Jósẹ́fù ní ìdí tí ó fi lè máa bínú tàbí ní ìkorò-ọkàn. A sọ́ sínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọ̀ nípa rẹ̀. Síbẹ̀, Jósẹ́fù tẹ̀síwájú láti máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ó sì ń sin adarí ọgbà-ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ọkàn kan. Fún ìdí èyí, a fi gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n sí abẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Nígbà tí àwọn olórí alásè ati agbọ́tí Fáráò, tí a so sẹ́wọ̀n, bẹ̀rẹ̀ sí ní fajúro, Jósẹ́fù ṣe aájò fún wọn. Ìkáàánú yìí ló mú kí agbọ́tí sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Fáráò lẹ́yìn tí Fáráò kò rí ẹnikẹ́ni láti túmọ̀ àlá tí ń bani lẹ́rù tí ó ní. Pẹ̀lú èyí, Jósẹ́fù kò gbìyànjú láti gbéraga. Ó sọ fún Fáráò wípé kòsí ẹlòmíràn lẹ́yìn Ọlọ́run tó lè túmọ̀ àlá. Nígbà náà ló tó wá sọ ìtumọ̀ tí Ọlọ́run fi fún-un.
Nítorí Jósẹ́fù jẹ́ olóòótọ́ nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n, Ọlọ́run mú jọba lóríi Íjíbítì (Lúùkù 16:10). Ní gbogbo ìkòríta ni Ọlọ́run ti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, tí ó sì ń fun ní ọgbọ̀n àti ìrírí láti lè tẹ̀lé ètò Rẹ̀.
Tí ìwúrí wa láti ṣiṣẹ́ bá ń wá látinú bí àwọn mìíràn ti ńṣe sí wa, àfọkàntán wa sí iṣẹ́ ma mẹ́hẹ. Àmọ́ tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lọ́jọọjọ́ ní ibi iṣẹ́ bá dá lé Ọlọ́run ńkọ́? Ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ wa bí ẹni ńṣe é fún Ọlọ́run yóò mú àbájáde tó tayọ wá. Lónìí, báwo lo ti lè mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Ọlọ́run pọ̀si lẹ́nu iṣẹ́?
Àdúrà
Baba, dárí jì mí fún àwọn ìgbà tí mo ti jẹ́kí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn ní ipá búburú lóríi iṣẹ́ mi. Mú ìgbàgbọ́ mi gbèrú síi láti lè jẹ́rìí wípé gbogbo iṣẹ́ ni yóò mú ògo bá orúkọ Rẹ. Lórúkọ Jésù. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Púpọ̀ nínú wa ni yíò lo bi ìdajì aiyé wa lágbà lẹ́nu iṣẹ́. Afẹ́ mọ̀ wípé iṣẹ́ wa ní ìtunmọ́ pé iṣẹ́ wa ṣẹ kókó. Ṣùgbọ́n áapon, ìpèníjà àti ìpọ́njú le mú kí a rí isẹ́ bi ohun líle tí aní láti là kọjá. Ètò yí yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ agbára tí o ní láti yan ìtunmọ̀ rere tí ó gbilẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ fún iṣẹ́ re
More