Fún Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Ìtunmọ̀Àpẹrẹ
A lè Yan Ìtumọ̀ tí Iṣẹ́ Wa Ní
Ní Jẹ́nẹ́sísì 37:5-7 àti 9, Jósẹ́fù lá àlá nípa ìpè ńlá tí Ọlọ́run gbé lé ayée rẹ̀. Àlá rẹ dálé bí yóò ti dé ipò agbára débi tí àwọn ẹbí rẹ̀ yóò wá wólẹ̀ fún-un. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní jowú wọ́n sì dìtẹ̀ láti yanjú àbúrò wọn. Nígbà tí wọ́n wà l'ájò tí Jósẹ́fù sì lọ bẹ̀ wọ́n wò, wọ́n lo ànfàní yìí láti tàá s'óko ẹrú. A lè sọ wípé, ìyẹ̀bá ńlá dé bá ìgbésí-ayé Jósẹ́fù.
Jósẹ́fù wá di ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì níbi tí àwọn ènìyàn ò ti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe láti yan ìhà tí ó ma kọ sí iṣẹ́ fún-un. Jósẹ́fù kò jẹ́ kí irú iṣẹ́ tó ńṣe darí ayé rẹ̀. Lóòótọ́ Potifa ni ọ̀gá rẹ̀, ṣùgbọ́n Jósẹ́fù yàn láti ṣe tirẹ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tó tayọ. Fún ìdí èyí, Ọlọ́run mú kí ó ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ̀, Potifa sì fi gbogbo ohun ìní rẹ̀ sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù.
Oníkálukú wa ló ní àfojúsùn irú iṣẹ́ tí a fẹ́. Bóyá iṣẹ́ tí ò ń ṣe nísinsìnyí kò pójú òṣùwọ̀n fún irú èyí tí o fẹ́. Bí a fẹ́ bí a kọ̀, a máa yàn – bóyá ní àìmọ̀ tàbí ìdàkejì – ìhà tí a ń kọ sí iṣẹ́. Ìtumọ̀ tí iṣẹ́ wa bá ní ni yóò mú wa pinu irú ìhà tí a maá kọ síi, èyí tí yóò wá ní ipa lóríi ìtara àti ìtayọ tí a ó fi ṣiṣẹ́, àti bí Ọlọ́run yóò ti lò wá sí.
A ní òmìnira láti yan ìtumọ̀ tí ó dára fún iṣẹ́ wa. Nígbà tí a bá ṣe èyí, yóò rọrùn fún wa láti ṣe iṣẹ́ lọ́nà tó tayọ, tí yóò sì mú kí àwọn mìíràn rí Kristi nínú ayée wa. Parí parí ẹ̀, àmì ìdánimọ̀ wa wà nínú Kristi, kìí ṣe nínú iṣẹ́ wa. Bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìtumọ̀ nínú iṣẹ́ tí ò ńṣe nínú ìjọba Rẹ̀.
Àdúrà
Ọlọ́run Baba, ràn mí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ mi bí Ìwọ ti ri lónìí. Ràn mí lọ́wọ́ láti rántí pé gbogbo iṣẹ́ tí ó tayọ tí mo ṣe nínú ìfẹ́ ni yóò fi ìfẹ́ Kristi hàn sí àwọn mìíràn. Jẹ́kí àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi rí Kristi nínú mi lónìí. Lórúkọ Jésù. Àmín.
Láti Ṣe Àwárí Síwájú Si
Ṣe àgbéyèwò àwọn ọ̀nà tí a fi lè rí ìtumọ̀ nínú iṣẹ́ wa tó kéré jùlọ lóríibuloogi Workmatters yí
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Púpọ̀ nínú wa ni yíò lo bi ìdajì aiyé wa lágbà lẹ́nu iṣẹ́. Afẹ́ mọ̀ wípé iṣẹ́ wa ní ìtunmọ́ pé iṣẹ́ wa ṣẹ kókó. Ṣùgbọ́n áapon, ìpèníjà àti ìpọ́njú le mú kí a rí isẹ́ bi ohun líle tí aní láti là kọjá. Ètò yí yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ agbára tí o ní láti yan ìtunmọ̀ rere tí ó gbilẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ fún iṣẹ́ re
More