Fún Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Ìtunmọ̀Àpẹrẹ
![Give Your Work Meaning](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12312%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọlọ́run A Máa Lo Iṣẹ́ Wa Fún Ètò Rẹ̀
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí ó kojú ìdánwò, àlá Jósẹ́fù padà wá sí ìmúṣẹ. Yàtọ̀ sí wípé Fáráò gbé ìṣàkóso gbogbo Íjíbítì le Jósẹ́fù lọ́wọ́, ìyàn mú kí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ wá tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ rẹ tí wọ́n sì wólẹ̀ fún àbúrò wọn, òtítọ́ sì ni wípé wọn kò mọ̀ lójú ẹsẹ̀ wípé òhun ni. Ọlọ́run ni lọ́kàn láti lo ọdún méje ọ̀pọ̀ àti ọdún méje ọ̀wọ́n-gógó láti darí àwọn ènìyàn Rẹ̀ lọ sí Íjíbítì fún ààbò. Ọlọ́run fi àwọn àdojúkọ náà pèsè Jósẹ́fù sílẹ̀ láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ.
Nígbà tí Jákọ́bù di olóògbé, àyà bẹ̀rẹ̀ sí ní fo àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù wípé yóò fẹ́ gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù fi ètò Ọlọ́run ṣe àfojúsùn ó sì fèsì wípé, “Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere […] láti dá ẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn sí” (Jẹ́nẹ́sísì 50:20). Díẹ̀ nínú ìwúlò Jósẹ́fù fún ètò Ọlọ́run tó gbòòrò ló hàn síi ní ìgbà ayé rẹ̀ bí àwa ti ń ri lónìí. Lọ́jọ́ kan, Jósẹ́fù yóò rí iye ẹ̀mí tí ohun ṣe ìrànwá fún ìgbàlà wọn.
Jákọ́bù 1:2-3 so fún wa wípé, “Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà.” Nígbà tí a bá dúró ṣinṣin lákòókò wàhálà, ṣe ni à ń ṣílẹ̀kùn fún àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run yóò gba ọwọ́ wa ṣe. Ó ṣe pàtàkì fúnwa láti jẹ́rìí wípé Ọlọ́run yóò lo iṣẹ́ wa láti tún ìhùwàsí wa ṣe, ró wa lágbára, àti láti gbé àwọn ǹkan ńlá ṣe èyí tó máa ṣòro láìsí ìrànwọ́.
Nígbà tí a bá fi Kristi ṣe àfojúsùn, a lè ní ìgboyà náà wípé Ọlọ́run ń lo iṣẹ́ wa ní àwọn ọ̀nà tó kọjá bí ojú inú wa ti lè rí lọ, gẹ́lẹ́ bí Jósẹ́fù ti ṣe. Lọ́jọ́ kan, gbogbo wa ma ní àǹfààní láti rí ipa tí ìṣòótọ́ wa kó nínú ètò Ọlọ́run.
Pe ara rẹ níjà láti gba Ọlọ́run láàyè fún ìsọdọ̀tun nípasẹ̀ àwọn ìrírí tí kò rọrùn, kí o sì gbé ìtumọ̀ iṣẹ́ rẹ lárugẹ fún ètò Rẹ̀ àti ògo Rẹ̀.
Àdúrà
Ọlọ́run Baba, mo mọ̀ wípé gbogbo ìgbà lò ń ṣiṣẹ́ nínú àti nípasẹ̀ ayéè mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti máa wo iṣẹ́ mi lójojúmọ́ pẹ̀lú ìrísí ayérayé. Fún mi ní ọgbọ́n nínú iṣẹ́ náà kí gbogbo ìṣe mi lè wúlò fún ètò rẹ. Lórúkọ Jésù. Àmín.
Láti ṣe àwárí síwájú si
Ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ètò mìíràn tó dá lóríi ibiṣẹ́ láti ọwọ́ Workmatters.
Nípa Ìpèsè yìí
![Give Your Work Meaning](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12312%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Púpọ̀ nínú wa ni yíò lo bi ìdajì aiyé wa lágbà lẹ́nu iṣẹ́. Afẹ́ mọ̀ wípé iṣẹ́ wa ní ìtunmọ́ pé iṣẹ́ wa ṣẹ kókó. Ṣùgbọ́n áapon, ìpèníjà àti ìpọ́njú le mú kí a rí isẹ́ bi ohun líle tí aní láti là kọjá. Ètò yí yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ agbára tí o ní láti yan ìtunmọ̀ rere tí ó gbilẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ fún iṣẹ́ re
More