O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe.
Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ:
Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun?
O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe.
O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀.
On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode.
O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade,
Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara:
O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode.
O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile.
O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wá wá, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà:
O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade.
O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi.
Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu.
Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu.
Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀.
Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.