Gẹn 39:7-23

Gẹn 39:7-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe. Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ: Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun? O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe. O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀. On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode. O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade, Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara: O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode. O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile. O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wá wá, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà: O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade. O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi. Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu. Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀. Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.

Gẹn 39:7-23 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀. Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé. Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé, ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo. Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.” Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé. Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí, ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.” Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi, ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé. Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.

Gẹn 39:7-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde. Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.” Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.” Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, OLúWA sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.