O. Daf 117:1-2

O. Daf 117:1-2 YBCV

Ẹ ma yìn Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède gbogbo: ẹ yìn i, ẹnyin enia gbogbo. Nitoriti iṣeun ãnu rẹ̀ pọ̀ si wa: ati otitọ Oluwa duro lailai. Ẹ yìn Oluwa!