ORIN DAFIDI 66

66
Orin Ìyìn ati Ọpẹ́
1Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun.
2Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀;
ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un!
3Ẹ sọ fún Ọlọrun pé,
“Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ,
agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,
tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ.
4Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́;
wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ,
wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”
5Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,
iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù.
6Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,
àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.
Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.
7Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.
Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.
8Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;
9ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,
tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.#(a) Eks 14:21 (b) Joṣ 3:14-17
10Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;
o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná.
11O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;
o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.
12O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,
a ti la iná ati omi kọjá;
sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.
13N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;
n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.
14Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,
tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú.
15N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ,
èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run,
n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ.
16Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun,
n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi.
17Mo ké pè é,
mo sì kọrin yìn ín.
18Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi,
OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.
19Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́;
ó sì ti dáhùn adura mi.
20Ìyìn ni fún Ọlọrun,
nítorí pé kò kọ adura mi;
kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 66: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀