ORIN DAFIDI 67

67
Orin Ọpẹ́
1Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa;
kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára;
2kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀;
kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀.
3Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;
jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
4Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,
kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,
nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;
o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
5Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;
jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
6Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;
Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa.
7Ọlọrun bukun wa,
kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 67: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀