ORIN DAFIDI 68

68
Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè
1Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.
Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀.
2Bí èéfín tií pòórá,
bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;
bí ìda tií yọ́ níwájú iná,
bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun.
3Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,
kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;
kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.
4Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,
ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.
OLUWA ni orúkọ rẹ̀;
ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,
ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́.
6Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;
ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,
ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.
7Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,
nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já,
8ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,
níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,
àní, níwájú Ọlọrun Israẹli.
9Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;
o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò.
10Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;
Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.#Eks 19:18
11OLUWA fọhùn,
ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.
12Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;
àwọn obinrin tí ó wà nílé,
13ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:
fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;
wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀.
14Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,
ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.
15Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;
Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ.
16Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,
kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,
ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae?
17OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀
pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun,
ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun.
18Ó gun òkè gíga,
ó kó àwọn eniyan nígbèkùn;
ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan,
ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá.
OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.
19Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa,
tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ.
20Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa;
OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú.#Efe 4:8
21Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀;
yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀.
22OLUWA ní,
“N óo kó wọn pada láti Baṣani,
n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun,
23kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín,
kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.”
24A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ,
pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn.
Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi,
bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀,
25àwọn akọrin níwájú,
àwọn onílù lẹ́yìn,
àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin.
26“Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan,
ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.”
27Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú,
ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda,
ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali.
28Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun,
fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn.
29Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu,
àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ.
30Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí;
àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè.
Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀;
fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká.
31Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,
kí àwọn ará Kuṣi#68:31 Orílẹ̀-èdè tí à ń pè ní Sudani lóde òní ni a pè ní Kuṣi ninu Bibeli . tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun.
32Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé;
ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA.
33Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé;
ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára.
34Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun,
ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli;
tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run.
35Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀,
Ọlọrun Israẹli;
òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára.
Ìyìn ni fún Ọlọrun!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 68: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa