ORIN DAFIDI 65

65
Ìyìn ati Ọpẹ́
1Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni,
ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún,
2ìwọ tí ń gbọ́ adura!
Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀,
3nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa,
ìwọ a máa dáríjì wá.
4Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn,
tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
láti máa gbé inú àgbàlá rẹ.
Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn,
àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ!
5Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn,
Ọlọrun olùgbàlà wa.
Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé,
ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré.
6Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀;
tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè.
7O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́,
ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀;
o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan.
8Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rù
nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ;
o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀.
9Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín,
o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú;
o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun,
o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀;
nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀.
10O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ,
o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀;
o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀,
o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.
11O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún;
gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko.
12Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn,
àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀,
13ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ,
ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì,
wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 65: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀