AISAYA 32:1-8

AISAYA 32:1-8 YCE

Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo, àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́. Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀, ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru. Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i, etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di. Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye, àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete. A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki. Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi. Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun, tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA; tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ, tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ. Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan. Wọn a máa pète ìkà, láti fi irọ́ pa àwọn talaka run, kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre. Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere, ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn.