Isaiah 32:1-8

Isaiah 32:1-8 YCB

Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀, àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀. Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè, àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege. A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn. Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi: òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan OLúWA kalẹ̀; ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò. Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́, ó ń gba èrò búburú láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà. Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró.