Isa 32:1-8

Isa 32:1-8 YBCV

KIYESI i, ọba kan yio jẹ li ododo, awọn olori yio fi idajọ ṣe akoso. Ẹnikan yio si jẹ bi ibi isápamọ́ kuro loju ẹfũfu, ati ãbo kuro lọwọ ijì; bi odo-omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata nla ni ilẹ gbigbẹ. Oju awọn ẹniti o riran kì yio ṣe baibai, ati eti awọn ti o ngbọ́ yio tẹ́ silẹ. Ọkàn awọn oniwàduwàdu yio mọ̀ oye, ahọn awọn akolòlo yio sọ̀rọ kedere. A kì yio tun pè alaigbọ́n ni ẹni-ọlá mọ, bẹ̃ni a kì yio pe ọ̀bàlújẹ́ ni ẹni pataki mọ. Nitori eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rẹ̀ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede, lati ṣe agabàgebe, ati lati ṣì ọ̀rọ sọ si Oluwa, lati sọ ọkàn ẹniti ebi npa di ofo, ati lati mu ki ohun-mimu awọn ti ongbẹ ngbẹ ki o dá. Ibi ni gbogbo ohun-elò enia-kenia jẹ pẹlu: on gbà èro buburu, lati fi ọ̀rọ eke pa talaka run, bi alaini tilẹ nsọ õtọ ọ̀rọ. Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.