AISAYA 32

32
Ọba tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé
1Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo,
àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́.
2Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́
ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà
Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀,
ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.
3Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i,
etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.
4Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye,
àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete.
5A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki.
6Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi.
Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun,
tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA;
tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ,
tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.
7Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan.
Wọn a máa pète ìkà,
láti fi irọ́ pa àwọn talaka run,
kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre.
8Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere,
ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn.
Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò
9Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,
ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,
ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.
10Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí i
ẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmú
nítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá,
èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́.
11Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,
kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,
ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò;
kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀.
12Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára,
ati nítorí àwọn àjàrà eléso;
13nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi.
Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀,
14nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin,
ìlú yóo tú, yóo di ahoro.
Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae,
yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,
ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.
15Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí,
títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wá
títí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso,
tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó.
16A óo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà,
ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo.
17Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia,
ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa,
ati igbẹkẹle OLUWA títí lae.
18Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia,
ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà.
19Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀,
a óo sì pa ìlú náà run patapata.
20Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀,
ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 32: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀