AISAYA 33

33
Adura fún Ìrànlọ́wọ́
1O gbé! Ìwọ tí ń panirun,
tí ẹnìkan kò parun,
ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀
nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́.
Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró,
nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run;
nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀,
nígbà náà ni a óo dà ọ́.
2Ṣàánú wa OLUWA,
ìwọ ni a dúró tí à ń wò.
Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ,
sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro.
3Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá,
wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀.
4A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko,
àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko.
5A gbé OLUWA ga!
Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;
yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni.
6Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.
Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,
ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.
7Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,
àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
8Òpópó ọ̀nà ṣófo,
àwọn èrò kò rìn mọ́;
wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,
wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;
wọ́n kò sì ka eniyan sí.
9Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,
ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,
gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.
Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,
igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.
OLUWA Kìlọ̀ fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀
10OLUWA ní:
“Ó yá tí n óo dìde,
ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.
Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.
11Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.
Èémí mi yóo jó yín run bí iná.
12Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,
tí wọ́n di eérú,
àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun.
13Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré,
ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe;
ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí,
ẹ kíyèsí agbára mi.”
14Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;
ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.
Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?
Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?
15Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,
ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,
tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,
tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.
16Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.
Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,
yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.
Ọjọ́ Ọ̀la tó Lógo
17Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;
ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.
18Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:
“Níbo ni akọ̀wé wà?
Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?
Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”
19Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,
àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,
tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́.
20Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún.
Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí,
tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae,
bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já.
21Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀,
yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa;
níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé,
ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.
22Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa,
òun ni alákòóso wa;
OLUWA ni ọba wa,
òun ni yóo gbà wá là.
23Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,
kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;
kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.
A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,
kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.
24Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé,
“Ara mi kò yá.”
A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 33: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀