AISAYA 34

34
Ọlọrun Yóo Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ níyà
1Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan.
Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,
kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde.
2Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,
inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀.
Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa.
3A óo wọ́ òkú wọn jùnù,
òkú wọn yóo máa rùn;
ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè.#Mat 24:29; Mak 13:25; Luk 21:26; Ifi 6:13-14
4Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànù
a óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé.
Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́
bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà,
àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́.
5Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run,
yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu;
yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun.
6OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀,
a rì í sinu ọ̀rá,
pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́,
ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò.
Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira,
yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu.
7Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn,
bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá.
Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀,
ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú.
8Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san,
ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni.
9Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà,
erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́;
ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà.
10Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú,#Ifi 14:11; 19:3
yóo máa rú èéfín sókè títí lae.
Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran,
ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae.
11Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé,
òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀.
OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí,
yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí.
12“Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é.
Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́.
13Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀,
ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀.
Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò,
14àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀,
àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn.
Iwin yóo rí ibi máa gbé,
yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀.
15Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí.
Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀,
yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀.
Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ,
olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀.
16Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA,
kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀.
Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀,
kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì.
Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀,
ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ.
17Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn,#Ais 63:1-6; Jer 49:7-22; Isi 25:12-14; 35:1-15; Amos 1:11-12; Ọbad 1-14; Mal 1:2-5
ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn.
Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae,
wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 34: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀