SAMUẸLI KEJI 23:24-39

SAMUẸLI KEJI 23:24-39 YCE

Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu. Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu; Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa; Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa; Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa; Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini; Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi; Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu; Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani; Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari; Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo; Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti; Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi; Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya. Ira ati Garebu, àwọn mejeeji jẹ́ ará Itiri; ati Uraya, ará Hiti. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ọmọ ogun náà jẹ́ mẹtadinlogoji.