SAMUẸLI KEJI 23

23
Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dafidi
1Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli:
2“Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
3Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀,
Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé,
‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba,
tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun,
4a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu,
ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu;
ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’
5“Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun,
nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo,
majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀.
Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi.
Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi.
6Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun
dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù,
kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú.
7Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀,
láti fi wọ́n jóná patapata.”
Àwọn Akọni Ọmọ Ogun Dafidi
(1Kron 11:10-41)
8Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo.
9Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. 10Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa.
11Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, 12ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà.
13Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. 14Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. 15Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” 16Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. 17Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe.
18Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn. 19Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́.
20Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. 21Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. 22Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. 23Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
24Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu. 25Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu; 26Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa; 27Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa; 28Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa; 29Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini; 30Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi; 31Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu; 32Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani; 33Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari; 34Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo; 35Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti; 36Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi; 37Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya. 38Ira ati Garebu, àwọn mejeeji jẹ́ ará Itiri; 39ati Uraya, ará Hiti.
Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ọmọ ogun náà jẹ́ mẹtadinlogoji.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KEJI 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀