Asaheli arakunrin Joabu si jasi ọkan ninu awọn ọgbọ̀n na; Elhanani ọmọ Dodo ti Betlehemu.
Ṣamma ara Harodi, Elika ara Harodi.
Helesi ara Palti, Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoa,
Abieseri ara Anetoti, Mebunnai Huṣatiti,
Salmoni Ahohiti, Maharai ara Netofa,
Helebu ọmọ Baana, ara Netofa, Ittai ọmọ Ribai ti Gibea ti awọn ọmọ Benjamini,
Benaia ara Piratoni, Hiddai ti afonifoji,
Abialboni ara Arba Asmafeti Barhumiti,
Eliahba ara Saalboni, Jaṣeni Gisoniti, Jonatani,
Ṣamma Harariti, Ahiamu ọmọ Ṣarari Harariti,
Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ara Maakha, Eliamu ọmọ Ahitofeli ara Giloni,
Hesrai ara Kermeli, Paari ara Arba,
Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ara Gadi,
Sekeli ara Ammoni, Nahari ara Beeroti, ẹniti o nru ihamọra Joabu ọmọ Seruia.
Ira ara Jattiri, Garebu ara Jattiri.
Uria ara Hitti: gbogbo wọn jẹ mẹtadilogoji.