Ìmọ́lẹ̀ Ayé - Ìfọkànsìn AdventiÀpẹrẹ

Light of the World - Advent Devotional

Ọjọ́ 3 nínú 4

Ayọ̀ 

Ayọ̀ Wa Tí Kò Lópin

Nípasẹ̀ Olùsọ́àgùntàn Sylvanus Elorm, Olùdarí àgbègbè ti Ìwọ Oòrùn Áfríkà

“Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: 'Ẹ má bẹ̀rù. Mo mú ìhìn rere ayọ̀ wá fún yín, èyí tí yóò mú ayọ̀ ńlá fún gbogbo ènìyàn.’” — Lúùkù 2:10

Ayé kún fún ayọ̀. Olúwa ti dé!

Bíbọ̀ Jésù Olúwa wa mú ayọ̀ tí kò ṣeé fẹnu sọ wá fún àwọn olùgbé ayé — ayọ̀ tó ń tẹ síwájú tó ń fún wa ní ìmọ̀lára tí a sì rí níbi gbogbo nígbà ọdún Kérésìmesì. Ó wà nínú ...

· Àwọn orin tí ó gbà gbogbo inú ilé àti ilé ìtajà gbogbo.

· Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó lẹ́wà tí wọ́n fi ń ṣe ilé lọ̀ṣọ̀

Ti ó fún wọn ní ìdùnnú ọkàn wọ́n á sì máa ń tà ara wọn lọrẹ.

· Àwọn ọmọdé kún àwọn òpópónà náà pẹ̀lú igbe ìdùnnú àti ayọ̀ ńláIlé.

Ayọ̀ ló jẹ́ kí ènìyàn púpọ̀ máa fí idán, àgbàyanu rántí ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ — a sì máa ń fi ojú sọ́nà dè é lọ́dọọdún. 

Ṣùgbọ́n kí ní ayọ̀ jẹ́? Oríṣiríṣi ìwé atúmọ̀ èdè sọ pé ó jẹ́ ayọ̀ ńlá — ṣùgbọ́n ọkàn wa mọ̀ pé ó ju pé ká kàn máa yọ̀ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún wa, ká máa rí àwọn ohun ìṣeré tó wù wá gbà ní gbogbo ìgbà, tàbí ká máa jẹ oúnjẹ aládùn pẹ̀lú àwọn tí a fẹ́ràn pẹ̀lú.

A lè ní Ìdùnnú fún ìgbà díẹ̀. Kò sì pẹ́ lọ títí. Ṣùgbọ́n ayọ̀ kì í tán — ipò ìdùnnú láì ká gbogbo àìdọ́gbá tí a ń kojú. Ayọ̀ gidi sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe pẹ̀lú bí Jésù ṣe wá sí ayé, nítorí bíbọ̀ Rẹ̀ mú ohun gbogbo wa ...

·Ìdáǹdè

·Ètùtù

·Ìtùnú

· Àlàáfíà

· Okun

· Òmìnira

· Ìgbàlà

Àti bẹẹ-bẹẹ lọ!

Ayọ̀ yìí — ayọ̀ ayérayé — ni ó yẹ kí a jẹ́ alábàápín pẹ̀lú gbogbo ènìyàn — pàápàá ní àkókò Kérésìmesì! 

Ní Kérésìmesì yìí, ẹ jẹ́ ká fi ìgboyà àti ìdùnnú kéde Ìhìn Rere náà kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè ní òmìnira àti ayọ̀ tí a ní nínú Jésù Kristi kí Ọ̀run sì kún fún ayọ̀ pẹ̀lú!

Kókó Ìjíròrò

Ayọ̀ wá di tiwa nítorí pé Ọlọ́run wá sí ayé. Báwo lo ṣe máa fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì yìí? Báwo lo ṣe lè fi ìdùnnú yí hàn sí áwọn tó wà láyìíká rẹ?

Àwọn Ẹ̀bẹ̀ Àdúrà

Gbadura fún Olùsọ́-àgùntàn Elorm ati awọn alabaṣiṣẹpọ̀ miiran — pe Ọlọrun yoo tẹsiwaju lati bukun iṣẹ-iranṣẹ wọn bi wọn ṣe jẹ́ alábàápín ayọ tirẹ pẹlu awọn ọmọde ati ọdọ ni ayika aye.

Gbàdúrà fún àwọn ọ̀dọ́ Orile-ede Sàró àti Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà — kí ayọ̀ Olúwa lè tàn kálẹ̀ nínú ọkàn wọn nínú ọdún Kérésìmesì yìí bí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìbí Kristi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí.

Gbàdúrà fún àwọn tó wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí wọn ò tíì mọ ayọ̀ tòótọ́ tó wà nínú Kérésìmesì. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè máa fi ìgboyà wàásù Ìhìn Rere náà fún wọn. 

Ayẹyẹ Kérésìmesì ní Orile-ede Saro  

Ọdún Kérésìmesì ni ayẹyẹ tó tóbi jù lọ! Ènìyàn pupọ ló máa ń kóra jọ fún àríyá àti àsè, tí wọ́n á máa jó kiri, tí wọ́n á sì máa yọ̀. Bọọlu afẹsẹgba kò gbẹ́hìn rárá — ere idaraya ti o gbajumọ julọ — tun wa ni akoko.

Ìrẹsì-ni oúnjẹ tí wọ́n máa ń jẹ ju ní oriẹ̀-èdè Sàró — èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìdílé tó jẹ́ tálákà jù lọ pàápàá láti rówó ra oúnjẹ àkànṣe yí. Ọbẹ̀ adìẹ tàbí ẹran míràn ní wọn sábà máa fí ń jẹ Ìrẹsì wọn

Àwọn ìdílé sábà máa ń rìnrìn àjò lọ sí ìlú abínibí àti abúlé wọn láti lọ ṣe àríyá pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́langba sábà máa ń gba aṣọ tuntun àti àwọn ẹ̀bùn míràn láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí àti àwọn ìbátan wọn míràn pẹ̀lú

Púpọ̀ nínú àwọn Kristẹni ló máa ń lọ sí ilé ìjọsìn fún àkókò kúkúrú lọ́jọ́ Kérésìmesì. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n hù nígbà tí wọ́n bí Kristi ni wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Light of the World - Advent Devotional

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni kárí ayé ni yíò ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dún yìí. Adventi, ayẹyẹ àpẹẹrẹ tí ó ní ẹwà tí yíò yọrí sí Ọjọ́ Kérésìmesì, jẹ́ apákan ńlá ti àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí o ṣe ń ka ìfọkànsìn Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Adventi yìí, ìwọ yóò ní ànfàní láti dara pọ̀ mọ́ra láti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ láti àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré, ìwọ ó sì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ojú ìwòye àti àwọn àṣà alágbára wọn.

More

A fé dúpe lówó OneHope fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, ṣe abẹ̀wò: http://onehope.net/