Ìmọ́lẹ̀ Ayé - Ìfọkànsìn AdventiÀpẹrẹ
Ìfinimọ̀nà
Nípasẹ̀ OneHope Ààrẹ Rob Hoskins
Àìmọye ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni kárí ayé ló máa ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dún yìí — bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe ń múra láti ṣe é.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò fi àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí o fẹ́ràn ṣe ayẹyẹ ọjọ́ pàtàkì yìí — bí orin Kérésìmesì kíkọ àti àwọn ìsìn tí wọ́n ń tàn àbẹ́là ṣe. Àwọn mìíràn yóò ṣe ayẹyẹ ìbí Olùgbàlà ní àwọn ọ̀nà tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún àṣà ìbílẹ̀ wọn — jíjẹ àwọn oúnjẹ olóórùn dídùn, ṣíṣe ayẹyẹ ní ọjọ́ mìíràn yàtò sì Oṣù ọpẹ 25, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ ṣe ìmúrasílẹ̀ ní Kentucky Fried Chicken!
Bí ẹ ti ń ka ìwé ìfọkànsin yìí, ẹ ó ní àǹfààní láti darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín láti àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà sí yín, kí ẹ sì jọ ṣayẹyẹ, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn èrò àti àṣà àrà ọ̀tọ̀ wọn.
Ọ̀kan lára irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ni Bíbọ̀ Jésù — ìyẹn ayẹyẹ kan tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ tó ń ṣamọ̀nà sí Ọjọ́ Kérésìmesì, ó sì kó ipa pàtàkì lára ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
Gbogbo ìrántí títan àbẹ́là kan ní ọjọ́ ìsinmi kan fún ọ̀sẹ̀ mẹrin, Bíbọ̀ Jésù sàfihàn Kristi gẹ́gẹ́ bí "Ìmọ́lẹ̀ Ayé". Abela kan dúró fún ẹgbẹ̀rún ọdún-eyi tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin, tí ó já sí àkókò tí ilé ayé tí ń dúró dè Olùgbàlà — tí ó sì ní ìtumọ̀ pàtàkì.
- Ọ̀sẹ̀ kini — Ìrètí. Lọ́jọ́ Ìsimi yìí, "Àbẹ́là Wòlíì" aláwọ̀ àlùkò kan ń rán wa létí pé Jésù ń bọ̀.
- Ọ̀sẹ̀ kejì — Ìfẹ́. Lọ́jọ́ Ìsimi yìí, àtùpà aláwọ̀ àlùkò kan tí wọ́n fi ń pè ní "Àbẹ́lá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù" ń rán wa létí ìrìn àjò Màríà àti Jósẹ́fù lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
- Ọ̀sẹ̀ kẹta — Ayọ̀. Lọ́jọ́ Ìsimi yìí, àlàwọ̀ aró kan tí wọ́n ń pè ní "Àbẹ́lá Olùsọ Àgùntàn" ń rán wa létí ìdùnnú tí ayé ní nígbà ìbí Olùgbàlà.
- Ọ̀sẹ̀ kẹrin — Àlàáfíà. Lọ́jọ́ Ìsimi yìí, "Àbẹ́lá Áńgẹ́lì" aláwọ̀ àlùkò ń rán wa létí ohun tí àwọn áńgẹ́lì ṣèlérí nínú Lúùkù 2:14 — àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé.
Pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọdún Bíbọ̀ Jésù yìí, mo gbà gbọ́ pé ìgbàgbọ́ yín yóò ní ìṣírí púpò bí ẹ ti ń ka àwọn ọ̀rọ̀ tó bọ́ sí ákòkò yìí, tó sì wúlò nípa Ìrètí, Ìfẹ́, Ayọ̀, àti Àlàáfíà.
Àkọsílẹ̀ ìfọkànsìn kọ̀ọ̀kan — tí alábàáṣiṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ OneHope kan tí ó ń sìn ní apá ibòmíràn lágbàáyé kọ — yóò fún ọ ní Ìwé Mímọ́ àti òye láti ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ yóò sì ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti ṣe ayẹyẹ bíbọ̀ Kristi ní ọ̀nà tuntun.
Ní áfikún, o tún lè rí àwọn àdúrà pàtó kan — fún ìwọ àti ìdílé rẹ, àti fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa kárí ayé lápapọ̀ láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń yí ìgbésí ayé padà dé ọ̀dọ́mọdé àti ọ̀dọ́langba — àti àwọn ohun amóríyá nípa àwọn àṣà Kérésìmesì àkànṣe láti àwọn àṣà ìbílẹ̀ mìíràn.
Ẹ ṣeun fún ṣíṣe ayẹyẹ Bíbọ̀ Jésù — àti ìbí Jésù Kristi — pẹ̀lú mi àti àwọn onígbàgbọ́ káàkiri àgbáyé! Mo dúpẹ́.
Kí Ọlọ́run bù kún ìwọ àti ìdílé rẹ lásìkò Kérésìmesì yìí. Kí ó kún fún ìrètí, ìfẹ́, ayọ̀ àti àlàáfíà tí Kristi nìkan ṣoṣo mú wá.
Ìrètí
Ìtàṣàn Ìmọ́lẹ̀
nipasẹ Hisho Uga tí ó jẹ́ Olùdarí agbegbe Peninsular Asia àti Japan
“Nítorí pé nínú ìrètí yìí ni a gbà wá là. Ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí rárá. Àwọn tó ń retí ohun tí wọ́n ti ní?” — Ìwé Róòmù 8:24
Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé àwòkẹ́kọ̀ jẹ́ àna mi, ó sì ṣe àwòkẹ́kọ̀ kan ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn nípa àwọn arábìnrin mẹ́ta tí wọ́n ti dàgbà, tí wọ́n ń gbay ara wọn ní ìyànjú lákókò ìṣòro.
Inú gbogbo ìdílé wa dùn gan - an nígbà tí a gbọ́ wipé ìwé ìròyìn orílẹ̀ - èdè kan máa gbé àgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àwòkẹ́kọ̀ náà jáde - àti pelu pé a tí ká nípa àkọsílẹ̀ náà
“Nínú eré yìí, ìrètí ń tàn bí dánnáewú”
Àgbéyẹ̀wọ̀ náà dára pupọ — ṣùgbọ́n àkíyèsí pàtàkì nipe ó ṣe àfihàn bí ìrètí ṣe jẹ́ gan - an.
Ìrètí kí ì ṣe iná tí ó hàn gedegbe, bí kò ṣe ìtànṣán iná. Kì í ṣe ìrókẹ̀kẹ̀ tí ó lè mí ilẹ̀ bí kò ṣe ìfọ̀hùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
Ìrètí wa dá lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ — àwọn ìlérí pé ògo Rẹ̀ yóò kún ilẹ̀ ayé bí omi ti ń bo òkun ... bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń gbé nínú ayé kan tó sábà máa ń dà bí òkùnkùn jú ìmọ́lẹ̀ lọ. Pàápàá julọ tí o bá ń gbé ní ibi tí àwọn Kristẹni kò ti wọ́pọ̀, bí orílẹ̀-èdè Japan.
Ẹ̀rí tó fi hàn pé a ní ìrètí lè máà tó nǹkan. Nígbà míràn, wọn kì í hàn rárá. Ṣùgbọ́n a lè rí ìtùnú nínú òtítọ́ náà pé Jésù — Ọba àwọn Ọba àti Olúwa àwọn Olúwa wa — fara hàn lẹ́ẹ̀kan náà, ní alẹ́ Kérésìmesì àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bí ọmọ jòjòló nínú ibùjẹ ẹran.
Ní àsìkò Kérésìmesì yí, ẹ jẹ́ kí a mọyì ẹwà ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn, èyí tí ó jẹ́ ìrètí wa — ní ìgbẹ́kẹ̀lé wípé ìmọ́lẹ̀ kékeré yí pàápàá yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ọlọ́run tí ó lẹ́wà, tí ó sì lágbára.
Kókó Ìjíròrò
Kíni ohun tí ó lè ṣe láti jẹ́ ìrètí ìtasánsán dánnáewú tó ń tàn nínú ayé tó ṣókùnkùn yí? Àwọn ọ̀nà kékèké wo ni Ọlọ́run lè fẹ́ lò ọ́ láti ní ipa tó lágbára ní àsìkò Kérésìmesì yí?
Àwọn Ẹ̀bẹ̀ Adura
Gbadura fun Hisho ati àwọn alabaṣiṣẹpọ OneHope wá míràn ti n ṣiṣẹ ní ibi àwọn òkùnkùn ni àyíká àgbáyé kí Ọlọ́run lè lo lati dá iná isoji ati tan imọlẹ ireti ni ọna ti o lagbara.
Gbàdúrà pé kí àwọn ọmọdé ní orílẹ̀-èdè Japan rí i pé kì í ṣe inú Bàbá Kérésìmesì ni ìrètí Kérésìmesì wà, bí kò ṣe nínú Kristi. Ẹ bẹ Ọlọ́run pé kí ó lo ìdùnnú tí wọ́n ní fún àsìkò ọdún láti fa àwọn ọ̀dọ́ àtàtà wọ̀nyí àti ìdílé wọn sún mọ́ Òun.
Ṣíṣé Ayẹyẹ Kérésìmesì ní Japan
"Àwọn ìtànná" Kérésìmesì ní ìfàlọ́kàn tí ó gbajúmò ní àwọn máa tan ìmọ́lẹ̀ kiri ní àwọn ibùdókọ̀ ojú irin, àwọn ọgbà ìtura, àti àwọn ibòmíràn tí áwọn ènìyàn ti máa ń rí àwọn ìmọ́lẹ̀ tó rẹwà.
Ìforúkọsílẹ̀ ní Kentucky Fried Chicken! Ó lè dà bí ohun tí kò bójú mú ṣùgbọ́n àṣà yìí ti fìdí múlẹ̀ dáadáa ní Japan. Ilé iṣẹ́ KFC a máa bẹ̀rẹ̀ sí gba àyè fún oúnjẹ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kejìlá — àti pé àwọn tí ó ti ṣètò nìkan ni yóò lè kó adìyẹ fún àsìkò ìsinmi!
Kérésìmesì jẹ isinmi fun awọn tọkọtaya (bii Ọjọ Falentaini). Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń jáde lọ sóde àríyá, wọ́n sì máa ń fún ara wọn ní ẹ́bùn dípò kí wọ́n máa wà pẹ̀lú ìdílé wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kò bá ní ẹni tí wọ́n máa bá ṣeré nígbà Kérésìmesì máa ń dá wa ni àwọn nìkan.
·Bàbá Kérésìmesì ni wọ́n sábà máa ń gbé lárugẹ nígbà ọdún jù Jésù lọ. Ní òdodo, púpọ̀ l àwọn ará Japan ni kò mọ̀ pé ayẹyẹ Kérésìmesì ọjọ́ ìbí Kristi. Síbẹ̀, ìdùnnú àti àjọ̀dún fún wọn ní anfani láti jáde lọ ì wàásù — nípa ṣíṣe àpéjọ, kíkọ orin Kérésìmesì ní ìta gbà ngba, àti àwọn agbekalẹ eto míràn.
Ní ọdún yìí, OneHope yóò pín àwọn ẹ̀dà ìwé tí KérésìmesìÌwé Ìrètí fún àwọn akẹ́kọ̀ ní ilé-ìwé àti níbi àjọ̀dún ọdún Kérésìmesì ní.
IDAGBASOKE Bọtini: ọjọ́ _1 ọjọ́ _1Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni kárí ayé ni yíò ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dún yìí. Adventi, ayẹyẹ àpẹẹrẹ tí ó ní ẹwà tí yíò yọrí sí Ọjọ́ Kérésìmesì, jẹ́ apákan ńlá ti àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí o ṣe ń ka ìfọkànsìn Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Adventi yìí, ìwọ yóò ní ànfàní láti dara pọ̀ mọ́ra láti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ láti àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré, ìwọ ó sì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ojú ìwòye àti àwọn àṣà alágbára wọn.
More