Ìmọ́lẹ̀ Ayé - Ìfọkànsìn AdventiÀpẹrẹ
Ìfẹ́
Olùkọ-Afárá
Láti ọwọ́ Osvaldo Carnival, Àlùfáà ní Catedral de la Fe, tí ó wà ní Buenos Aires, Argentina
“'Wúńdíá náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli' (èyí tí ó túmọ̀ sí, 'Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa')."— Matiu 1:23
Lára àwọn oríṣiríṣi àwọn iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga, afárá kíkọ́ jẹ́ ìgbìyànjú pàtàkì kan.
Gẹ́gẹ́bí Boreham, ònkọ̀wé olókìkí ìlú Australia, ṣe ṣe àkíyèsí àkọsílẹ̀ nípa gbajúmò olùkọ́-afárá kan:
Àwọn ìṣẹ́gun tí ó ní nípa ígboyà rẹ̀ àti àwọn àṣeyọrí tí ó yanilẹ́nu mú mi pinnu pé ó tọ́ láti ya ìgbésí ayé ènìyàn sọ́tọ̀ sí iṣẹ́ ti kíkọ́ àwọn afárá. Ó jẹ́ ohun tí ó ní ẹwà láti ríi bí, afárá tí ó gbòòrò ṣe rékọjá àwọn ọ̀gbùn tí ó jinlẹ̀ àti àwọn odò tí ó ń ru, lọ sí òdì-kejì tí ó gba àwọn ọmọdé láyè láti kọjá lórí rẹ̀ láìléwu. Lọ́nà kan náà, àwọn afárá ìbánidọ́rẹ̀ àti ìfẹ́ inú rere tún lè ṣe àkótán àwọn ìyàtọ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
Ní àwọn ọjọ́ tí ó nira wọ̀nyi - nígbàtí àwọn ènìyàn bá ń ya ara wọn kúrò lọ́dọ̀ ara wọn, tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin bá ní ìyàsọ́tọ̀ nípasẹ̀ ìṣèlú, ẹ̀yà, tàbí láàrin akọ àti abo - ó ṣe pàtàkì púpọ̀ ó sì ṣe dandan láti kọ́ àwọn afárá àsopọ̀ àti ìfẹ́.
• A lè mú Ìmotara-ẹni-nìkan kúrò nípasẹ afárá àánú.
• Ìkóríra àti inúnibíni kò lè dúró níbití afárá inú rere àti ayọ̀ bá wa.
• Àwọn ìwà búburú ti o waye nípa ẹ̀ṣẹ̀ yíò bẹ̀rẹ̀ sí subú ní kété tí a bá kọ́ afárá lọ sínú òdodo.
Ẹjẹ́ ki a gbe Jésù Krístì yẹ̀ wò—Òun ní Olùkọ́-afárá tí o gá jùlọ ní gbogbo ìgbà. Lílo àwọn ohun èlò ti ìgbésí ayé Rẹ̀ - Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ibi-ìrẹ̀lẹ̀ Rẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran - Ó kọ́ afárá láti aiyé sí ọ̀run, àti láti ikú sí ìyè.
Nípa ìgbé ayé àpẹẹrẹ Rẹ̀, ìwọ, pàápàá, le kọ́ àwọn afárá kí o sì mú ìlàjà wá sí ayé tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ní inú ọdún Kérésìmesì tí a fẹ́ ṣe yí!
Ọlọ́run ti pèsè àwọn ohun èlò tí o nílò sílẹ̀: ìdáríjì, inú rere, àti ìwúrí nípa Ọ̀rọ̀ Rẹ. Lo ànfàní yìí láti lo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí - pàápàá ní àkókò bíbọ̀ Jésù yí - láti jẹ alábápín ìfẹ́ afárá-kíkọ́ Rẹ pẹ̀lú áwọn tí ó wà ní àyíká rẹ.
Kókó Ìjíròrò
Àwọn ìpínyà àti ìyàtọ̀ wo ni o rí ní agbègbè rẹ, láàrin àwọn ojúlùmọ̀ rẹ? Àwọn afárá wo ni o lè kọ́ láti mú ìsọ̀kan wà àti jẹ́ alábápín ìfẹ́ ti Jésù Kristi ní àwọn irú ipò yí?
Àwọn Ẹ̀bẹ̀ Àdúrà
Gba àdúrà fún Osvaldo àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Ìrètíkan wa tí ń ṣiṣẹ́ ní Gúúsù àti Àárín gbùngbùn America. Bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àfihàn ìfẹ́ tí ó mú Jésù wá sí ayé sí ọ̀dọ̀ ọ̀kọ̀-ọ̀kan àti gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n níí ṣe pẹ̀lú.
Gba àdúrà fún àwọn ọ̀dọ́ Argentina, pé kí Ọlọ́run bùkún àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì wọn láti mú ìsọ̀kan wá sí àwọn ìdílè tí ó tí dàrú àti àwọn agbègbè tí ó ní ìpalára nípasẹ̀ Ara Krístì.
Gbàdúrà sí Ọlọ́run kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn nínú ìdílé rẹ...ní àdúgbò rẹ...nínú ìjọ rẹ...àti kárí ayé. Bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn afárá níbití wọ́n tí nílò wọn jùlọ.
Síṣe Ayẹyẹ Kérésìmesì ní ìlú Argentina
Oṣù Kejìlá jẹ́ osù ooru ní ìhà gúsù. Pẹ̀lú áwọn ìwọ̀n òtútù tí ó ju 95°F, ìwọ kì yóó rí Kérésìmesì funfun òní yìnyín ní Argentina!
Láìbìkítà nípa ooru, àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ tí kálórì wọn ga (tí a mú bọ̀ láti ilẹ̀ Europe, níbití àkókò Kérésìmesì ti tutù púpọ̀) ni a pèsè. Àwọn oúnjẹ tí óní àwọn èròjà púpọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èso tí ó gbẹ tún wọ́pọ̀ níbẹ̀.
Ayẹyẹ gangan má n wáyé ní àsálẹ àìsùn Kérésìmesì - pẹ̀lú oúnjẹ nlá kan, oúnjẹ àjọ̀dún tí a ó jẹ ní ìrọ̀lẹ́ mọ́ alẹ́ (ní bíi agogo mẹ́wàá tàbí agogo mọ́kànlá alẹ́), lẹ́yìn ẹ̀yíi ni a ó máa ṣe àwọn eré iná àti àwọn àtùpà ìwé ìbílẹ̀ ní àárín ọ̀gànjọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń wà lójúfò ní gbogbo òru mọ́jú!
Ọjọ́ Kérésìmesì máa ń jẹ́ ọjọ́ tí púpọ̀ nínú wọn fẹ́ràn láti fi ara balẹ̀ lò pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni kárí ayé ni yíò ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dún yìí. Adventi, ayẹyẹ àpẹẹrẹ tí ó ní ẹwà tí yíò yọrí sí Ọjọ́ Kérésìmesì, jẹ́ apákan ńlá ti àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí o ṣe ń ka ìfọkànsìn Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Adventi yìí, ìwọ yóò ní ànfàní láti dara pọ̀ mọ́ra láti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ láti àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré, ìwọ ó sì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ojú ìwòye àti àwọn àṣà alágbára wọn.
More