Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ààyè Ìsinmi Àpẹrẹ

Breathing Room

Ọjọ́ 5 nínú 5

Mo gbà: atẹ́-ènìyàn-l'ọ́rùn ni mí. (Ìwọ pẹ̀lú àbí?) Àmọ́, mo wá ṣe àkíyèsí wípé ohun kan wà tí kò sí nínú àkọlé yẹn. Jíjẹ́ atẹ́-ènìyàn-l'ọ́rùn tún jásí wípé mo jẹ́ ajá-ènìyàn-kulẹ̀. Tí mo bá ṣiṣẹ́ dalẹ́ láti tẹ́ ọ̀gá mi lọ́run èyí lè mú mi já ọ̀rẹ́ tí a jọ fẹ́ lọ gbafẹ́ kulẹ̀. Dídarapọ̀ mọ́ ìkórajọpọ̀ àwọn olùkàwé lè dí ọ lọ́wọ́ láti bá ẹbí rẹ jẹun alẹ́. O ò rí ǹkan bí? Gbogbo èsì bẹ́ẹ̀ni tí o fi láti tẹ́ ẹnìkan lọ́run ló máa padà jásí rárá sí ẹlòmíì tòsí lè yọrí sí ìjákulẹ̀.

Tí o bá dàbí èmi, o ma ń jìyà fún àwọn ẹlòmíràn tí ò ń tẹ́lọ́rùn yí nípa dídẹ́kun láti fún ara rẹ ní ìsinmi àti wípé o máa ń gbìyànjú láti ṣe gbogbo iṣẹ́ tó ń jẹyọ ní sàkánì rẹ. Mo máa jẹun alẹ́ nílé mo sì máa fi ìṣẹ́jú mélòó kan pẹ́ dé ìkórajọpọ̀ àwọn olùkàwé! 

Bí a ṣe ń mú ètò kíkà nípa ààyè ìsinmi yìí wá sí ìdánudúró, mo fẹ́ sọ ìtàn kan látinú Májẹ̀mú Láéláé—pàápàá ẹsẹ̀ Bíbélì kan—tó mú àyípadà dé bá ipele ayé mi kan. Fún ọgọọgọ̀rún ọdún ṣáájú ìbí Jésù, wọ́n ti lékè ìlú Jerúsálẹ́mù, èyí tójù nínú rẹ̀ ni a sì ti wó lulẹ̀. Títún odi ìlú náà kọ́ wá bọ́ sí kánjúkánjú, Nehemáyà sì ni ẹni tí ń darí iṣẹ́ náà. Lọ́jọ́ kan, ó rí ìwé ìpè gbà, èsì rẹ̀ sí ìwé ìpè náà ti wá di atọ́nà fún mi. Nehemáyà sọ wípé, “...mò ńṣe iṣẹ́ pàtàkì kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní da kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àti wá ríi yín.”

Nígbàtí mo kọ́kọ́ ka ẹsẹ̀ Bíbélì yí, mo ní àwọn ọmọdé mẹ́ta nílé, mo sì ń kọ́ èyí tó dàgbà jù gẹ́gẹ́bí olùkọ́-ilé, ọkọ mi sì wà lẹ́nu ṣíṣe ìdásílẹ̀ ìjọ. A kò ní ààyè ìsinmi bótiwù kó mọ. Síbẹ̀, ó nira fúnmi láti kọ àwọn ìfìwépè àti onírúurú àǹfààní tó ń yọjú.

Ǹkan tí mo ṣàkíyèsí nínú èsì Nehemáyà ni ìgbara-ẹni-láyè láti fi àwọn ènìyàn tó ṣe pàtàkì jùlọ láyé wa ṣáájú. Wípé mo jẹ́ màmá ni “iṣẹ́ pàtàkì tí mo ní lọ́wọ́.” N kò sì lè “sọ̀kalẹ̀ wa” láti darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ yẹn tàbí láti sọ̀rọ̀ níbi ìpérajọpọ̀ àwọn obìnrin tí ẹ pè mí sí. Sísọ bẹ́ẹ̀ni sí àwọn ǹkan wọ̀nyí ma túmọ̀ sí sísọ rárá sí “iṣẹ́ pàtàkì tí mo ní lọ́wọ́” nínú ẹbí. 

Ẹyín obìnrin, a lè jọ̀wọ́ ara wa, àkókò wa, owó wa, àti ààyè ìsinmi wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò ní sí ǹkankan nílẹ̀ fún àwọn tí a fẹ́ràn jùlọ bíkòṣe ràlẹ̀rálẹ̀. Dípò èyí, ẹ jẹ́kí a mú ààyè ìsinmi wa padà bọ̀ sípò nípasẹ̀ fífún àwọn tí a fẹ́ràn ní àǹfààní ìṣáájú sí wa. Wàyí sí àwọn ǹkan tó kù, a lè fèsì wípé, “mò ńṣe iṣẹ́ pàtàkì kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá.”

Tí o bá jẹ̀gbádùn ètò kíkà yí, wo fọ́nrán ẹ̀kọ́ amóhùn-máwòrán onípa-mẹ́rin tí a ti mú ètò kíkà náà jáde nípasẹ̀ ṣíṣe ìgbàsílẹ̀ áàpù Ààyè Ìsinmi lọ́fẹ̀ẹ́

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Breathing Room

Ǹjẹ́ ó máa ń rí lára ni ìgbàkígbà wipé ó kò gbádùn ohunkóhun nítorí ó ñ gbìyànjú láti se gbogbo ohun? Ó nse opọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan nipase ònà rè ni ayé pèlú àwon ololufe rè. . .Ó jafafa. Sùgbọ́n ó n sàárẹ̀. Ó kan ní-lò àyè ...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ North Point Ministries àti Sandra Stanley fun ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: http://breathingroom.org

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa