Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ààyè Ìsinmi Àpẹrẹ

Breathing Room

Ọjọ́ 3 nínú 5

Bí o bá ti ṣe ọjọ́ ìbí rí, gbáradì fún ìdánwò, ṣe ìgbéyàwó, bímọ tàbí ṣ'àjọyọ̀ Kérésìmesì, ǹjẹ́ o tí "ka iye ọjọ́ rẹ." Ó ṣeéṣe kí o má ṣe àpèjúwe rẹ̀ báyẹn, ṣùgbọ́n o mọ pàtó iye ọjọ́ ọjà, ọjọ́ ìgbáradì tàbí iye ọjọ́ tó kù kí ayẹyẹ ńlá yẹn tóó dé.

Nínú ẹsẹ tònìí láti inú Sáàmù 90, Mósè ń bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí Ó ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú òye kooro tí a máa ń ní tí a bá wà lábẹ́ gbèdéke kan —“kọ́ wá láti ka iye ọjọ́ wa.” Nígbàtí Kérésìmesì bá ku ọjọ́ mẹ́ta tí o sì ní láti ra àwọn ẹ̀bùn síi, o kò nìí k'ásẹ̀ l'ẹ́sẹ̀ lórí àga kí o máa wo sinimá aláfẹ́. O ní àwọn ǹkan pàtàkì láti ṣe. Mímọ̀ pé oò ní àsìkò púpọ̀ yíò mú ọ ṣe ìkáwọ́ ohun tí wàá fi àsìkò rẹ ṣe.

Gbogbo ìgbà ni ayẹyẹ yíò wà tó yẹ k'á lọ, iṣẹ́ àkànṣe láti ṣe, ìgbìmọ̀ láti darapọ̀ mọ́, ìrìnàjò láti rìn, àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe. Ẹ̀rù yíò sì wí kẹ́lẹ́ sí ọ pé ìbá dára kí o ṣe gbogbo wọn àìjẹ́bẹ́ẹ̀ oò ní kún ojú òṣùwọ̀n. Ṣùgbọ́n kíkà iye ọjọ́ rẹ dàbíi mímú gbogbo ohun wọ̀nyẹn ṣe pẹ̀lú ìdínwọ̀n. Àwọn ènìyàn àti ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ní oò kọ̀ mú ṣe.

Ìgbìmọ̀ tí o fi ìtìjú darapọ̀ mọ́? Kò sí ààyè fún yẹn. Ìrìnàjò iṣẹ́ tí yíò mú ọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ fún gbogbo ọ̀sẹ̀? Rárá, kìí ṣe nísinsìnyí.

Nígbàtí a bá bẹ̀rẹ̀ síí ríi pé àkókò wa kéré, a ó lè fi ọgbọ́n pinnu ohun tàbí pàtàkì jùlọ ẹni, tí ó yẹ fun àkókò péréte wa. Mósè sọ wípé a ó “ní ọkàn ọgbọ́n.” Bí ó bá jẹ́ pé iṣẹ́ pá ọ lórí, o ti farajì jù, tàbí ọkàn rẹ p'ami, gbíyànjú láti ka iye ọjọ́ rẹ. Gbà pé (bíótilẹ̀jẹ́pé o lérò láti gbé ayé fún bíi ọdúnmọ́dún síi) àkókò rẹ kéré, nítorí náà o ní láti dín ohun tí ò ń fi àkókò rẹ ṣe kù. Mo ṣ'èlérí, lílo àwọn ìdínwọ̀n filter yíò fún ọ ní ààyè ìsinmi tí o tí ń wá nínú kàlẹ́ńdà rẹ.

L'ọ́la a ó wo irúfẹ́ ìdínwọ̀n míràn tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ààyè ìsinmi wá sínú ìsúnná rẹ. K'ótó d'ìgbà náà, bi ara rẹ: Kíni ipò tàbí ohun náà tí mi ò fẹ́ẹ́ lo àkókò péréte mí lé lórí mọ́?

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Breathing Room

Ǹjẹ́ ó máa ń rí lára ni ìgbàkígbà wipé ó kò gbádùn ohunkóhun nítorí ó ñ gbìyànjú láti se gbogbo ohun? Ó nse opọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan nipase ònà rè ni ayé pèlú àwon ololufe rè. . .Ó jafafa. Sùgbọ́n ó n sàárẹ̀. Ó kan ní-lò àyè ...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ North Point Ministries àti Sandra Stanley fun ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: http://breathingroom.org

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa