Ààyè Ìsinmi Àpẹrẹ
Nínú gbogbo rúdurùdu ojoojúmọ́ tí ìpàdé, ayẹyẹ, ojúṣe, ìkó ọmọ lùbọ́ nínú ọkọ, títọ́jú àgbà ẹni, ṣíṣe íṣẹ́ sin elòmíràn, wíwá "àsìkò fún ara mi,” jíjẹ́ iṣẹ́, sísáré káàkiri ìlú, pínpín ara mi lónìí àti lílo gbogbo agbára mi tàn . . . Mo máa ń fẹ́ ní sàn-án sàn-án láti “dùbúlẹ̀ ní pápá oko tútù,” tàbí jókòó “níhà omi dídàkẹ́ rọ́rọ́.” (Bíótilẹ̀jẹ́pé Ife kọfí kan ni n ó jókòó tì lẹ́yìnkùlé. Ìwo ńkó?)
A níilò ààyè ìsinmi.
Ààyè ìsinmi ní ààyè láàrin ìṣísẹ̀ rẹ àti ibi gbèdéke rẹ. Ó jẹ́ ìjíròrò tí a kò kánjú sọ pẹ̀lú ọ̀rẹ́minú ẹni. Ó jẹ́ oúnjẹ́ tí a jókòó jẹ nínú ilé kìí ṣe èyí tí a dá'kà jẹ. Ó jẹ́ fífi fúnni tinútinú nítorípé o kò ì tíì ná gbogbo owó tí o pa tàn. Ààyè ìsinmi ní ìgbé-ayé tí a mọ̀ọ́mọ̀ gbé ní jẹ̀lẹ́nkẹ́, níwọ̀nba, àti ní yíyan ohun tó ṣe pàtàkì jú nínú rẹ̀.
Mo mọ̀ pé wà a gbà pẹ̀lú mi pé irú ìgbé-ayé yìí dùn un gbọ́ létí ju ti hílàhílo, apinnilẹ́mìi tíi mú ni dàbí ẹni pé a ṣe ju ara ẹni lọ tàbí wà ní ìdààmúdààbo. Síbẹ̀ bí a bá wo àkọsílẹ̀ ohun tí o ní láti ṣe tàbí kàlẹ́ńdà rẹ a o ríi pé—bíi tí ọ̀pọ̀ nínú wa—ò ń tiraka láti tẹ̀ẹ́ kẹ́jẹ́.
Ǹjẹ́ kíni ohun tí ó ń tì ọ́ láti kọjá gbèdéke rẹ?
Ó ṣòro láti ṣe ìdánimọ̀ rẹ̀ ó sì tún ṣòro síi làti gbà, ṣùgbọ́n fún èmi, ẹrù ni. Mo bẹ̀rù kí wọ́n yọ ọwọ́ kílàńkó mi l'áwo, nítorí náà màá tiraka láti wá ààyè fún àsè alẹ́ pẹ̀lù àwọn ọ̀rẹ́bìnrin mi bíótilẹ̀jẹ́pé ó ti rẹ̀ mí d'ọ́ba. Mo bẹ̀rù kí á já mi jù s'ẹ́yìn, nítorí náà màá ṣe àwárí lórí ìkànnì ayélujára fún ọkọ̀ tuntun bíótilẹ̀jépé kò sí ohun tó ṣe okọ̀ mi. Mo bẹ̀rù kí n já ènìyàn kulẹ̀, nítorí náà màá gbà láti darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ bíótilẹ̀jẹ́pé mi ò ní ìtara fún iṣẹ́ àgbàṣe náà . . . ṣé gbogbo ohun wọ̀nyí kò ṣe àjèjì sí ọ?
Ẹ̀rù a máa wí kẹ́lẹ́ fún wa pé à ń já wa jù sílẹ̀ tàbí já wa jù s'ẹ́yìn, nítorí náà a ó kó jú ohun tí a lè ṣe lọ a ó sì bá àwọn àpò ìfowópamọ́sí wa kanlẹ̀ gbẹ̀rẹ̀. Ẹ̀rù a máa jí ààyè ìsinmi wa. Ǹjẹ́ o mọ àṣẹ́ tí a pa léraléra jù nínú gbogbo Bíbélì? Má bẹ̀rù. Ọlọ́run sọ fún wa pé kí a má gba ẹ̀rù láàyè láti kó wa l'áyà jẹ. Ó fún wa ní ọ̀nà ìrọ̀rùn láti borí rẹ̀.
L'ọ́la a ó wo ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà pè wá (fún bíi ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún) láti mú àwọn ààyè ìsinmi padà wá sí ayé wa. Kí ó tó di ìgbà náà, wo kàlẹ́ńdà rẹ kí o sì bèèrè pé: Kíni ohun kan tí mo gbà láti ṣe nítorípé mo bẹ̀rù kí á má já mi sílẹ̀ tàbí já ẹlòmíràn kulẹ̀ nítorí mi ò fẹ́ kọ̀ fún wọn?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ ó máa ń rí lára ni ìgbàkígbà wipé ó kò gbádùn ohunkóhun nítorí ó ñ gbìyànjú láti se gbogbo ohun? Ó nse opọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan nipase ònà rè ni ayé pèlú àwon ololufe rè. . .Ó jafafa. Sùgbọ́n ó n sàárẹ̀. Ó kan ní-lò àyè èémi die. Pèlú ipèwá sókí onìyàlénu kan, Olórun pèsè ònà láti ropo ìyára rè to dùn kọjá ààlà fun èyí to ma mu àlàáfíà wa ni ìkẹyìn. Ètò yìí ma fi báwo hàn é.
More