Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́Àpẹrẹ
Oore-ọ̀fẹ́, Oore-ọ̀fẹ́ Parí rẹ̀.
Mo ti ja ìjà rere, mo ti parí iré Ìje, mo sì wà bí olóòótọ́.
Èṣù kò bẹ̀rù wa nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan. Ẹ̀rù a máa bà á lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí a bá fẹ́ parí rẹ̀ dáadáa. Ó ti rí kí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ nǹkan ṣùgbọ́n kí wọ́n má parí rẹ̀. Ó ti wà pẹ́ tó láti mọ̀ pé ohun tó jà jù ni bí ó bá ṣe parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún ọ.
'Píparí dára ju bí bẹ̀rẹ̀...'
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni tí ó bá forí tìí dópin ni a ó gbà là. Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan ló lè mú ni faradà dópin. Ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ níbi gbogbo ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ti tutù ṣùgbọ́n nípa Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a ó parí dáadáa ní orúkọ Jésù. Ọlọ́run sọ fún Serubábélì, "Kìí ṣe nípa ipá, kìí ṣe nípa agbára ṣùgbọ́n nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run. Ẹ̀mí Ọlọ́run níí fún ni ní Oore-ọ̀fẹ́ láti parí dáradára. Ní ẹsẹ tó tẹ̀lé ẹ, kò sí ohunkóhun, kódà òkè ńlá kò le dúró níwájú Serubábélì; yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú rẹ̀! Àti nígbà tí Serubábélì gbé òkúta ÌKẸYÌNtí tẹ́mpìlì sí pò, àwọn ènìyàn yóò pariwo: Oore-ọ̀fẹ́, Oore-ọ̀fẹ́ sí í. '
Oore-ọ̀fẹ́ bẹ̀rẹ̀ rẹ̀! Oore-ọ̀fẹ́ yóò parí rẹ̀! Oore-ọ̀fẹ́! Oore-ọ̀fẹ́! Ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ń wò wá. Ó ti ń wò wá kí a tó bí wa àti níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀, yóò rí i dájú pé nípa Oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, a ó parí ohun gbogbo dáradára tí a sì gbé òkúta ìkẹyìn sípò rẹ̀ kí a tó mí ìmí ìkẹyìn.
' Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún mi pé, "Wòó Jeremáyà! Kí lo rí?"Mo sì dáhùn, " Mo rí ẹ̀ka igi álmọ́nì" ' Ọlọ́run sì wí pé, "Bẹ́ẹ̀ ni, èyí sì túmọ̀ sí pé mò ń wò, ń o sì mú èròǹgbà mi ṣẹ."
Nípa Ìpèsè yìí
Oore-ọ̀fẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run tí kòdá lórí ohunkóhun tí a ṣe tàbí tóṣe. ó mú wa tọ́ lojú Ọlọ́run. Nípa rẹ̀ ni a gbàwá là. Nípa rẹ̀ lafi lè béèrè ìdáríjì. Kòwà k’ẹ̀ṣẹ̀ máa pọ̀sí. Kìí ṣ’èrè ohun rere tí a ṣe, kò sẹ́ni tí ó lè fọ́nnu nípa rẹ̀. A mọ́ pé ìrìn pẹ̀lú Ọlọ́run kìí ṣe nípa ipá tàbí agbára ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí tó fún wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/