Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́Àpẹrẹ

Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́

Ọjọ́ 1 nínú 3

Oore-ọ̀fẹ́ ; Oore-ọ̀fẹ́ bẹ̀rẹ̀ rẹ̀

Who art thou, O great mountain? before Zerubbabel thou shalt become a plain: and he shall bring forth the headstone thereof with shoutings, crying, Grace, grace unto it. Zechariah 4:7 KJV

Taa ni ìwọ òkè ńlá? níwájú Serubábélì ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀: ò n ó sì fi ariwo mú Òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yíò máa kígbe wí pé oore-ọ̀fẹ́, oore-ọ̀fẹ́ síi

A sábà máa ń rí ìdojú kọ nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan tuntun. Ó lè jẹ́ iṣẹ́ tuntun, ìgbéyàwó, ìbádọ́rẹ̀, iṣẹ́ àkànṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀ síbẹ̀, ohunkóhun tó wù kó jẹ́, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó láti sọ gbogbo àwọn òkè di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo Nehemáyà. Lọ́gán tí ó pinnu láti mọ odi Jerúsálẹ́mù, Sáńbálátì ará Horoni àti Tobáyà ìránṣẹ́ Ámónì kojú rẹ̀. Níní wàhálà kìí ṣe àìní oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Dípò, ó jẹ́ àkókò èyí tí oore-ọ̀fẹ́ lè farahàn jù lọ

Neh 4:7-9

[7] Ṣùgbọ́n nígbà tí Sáńbálátì àti Tobáyà àti àwọn ará Árábù àti àwọn ará Ámónì àti àwọn ará Áṣídódì gbọ́ nípa àtúnṣe àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù ń tẹ̀síwájúàti wí pé àwọn àlàfo náà ti ń dí pa, inú bí wọn gidigidi. [8]Wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti wá dojú ìjà kọ Jerúsálẹ́mù àti láti fa ìdàrúdàpọ̀ nínú rẹ̀ [9] A sì gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì ṣe ààbò lòdì sí wọn ní ọ̀sán àti ní òru. (ESV)

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdojúkọ láti ọ̀dọ̀ wọn, Ọlọ́run fún wọn ní oore-ọ̀fẹ́ láti parí iṣẹ́ náà. Òótọ́ ni pé, Ọlọ́run kò ní fún wa ju bí a ṣe lè kojú àti wí pé oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fún wa. Ìdí nìyí tí a kò fi lè ṣe aláìgbàdúrà. A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà nígbà gbogbo fún oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀nà ayé wa gbogbo. Ẹ jẹ́ ká tọ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú àti oore-ọ̀fẹ́ gbà tí yóò rán wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro wá. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó láti bẹ̀rẹ̀ àti láti parí iṣẹ́.

Ó sì dá mi lójú pé Ọlọ́run, tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú rẹ, yóò tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ rẹ̀ títí yóò fi parí rẹ̀ ní ọjọ́ ìpadàbọ̀ Jésù Krístì.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́

Oore-ọ̀fẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run tí kòdá lórí ohunkóhun tí a ṣe tàbí tóṣe. ó mú wa tọ́ lojú Ọlọ́run. Nípa rẹ̀ ni a gbàwá là. Nípa rẹ̀ lafi lè béèrè ìdáríjì. Kòwà k’ẹ̀ṣẹ̀ máa pọ̀sí. Kìí ṣ’èrè ohun rere tí a ṣe, kò sẹ́ni tí ó lè fọ́nnu nípa rẹ̀. A mọ́ pé ìrìn pẹ̀lú Ọlọ́run kìí ṣe nípa ipá tàbí agbára ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí tó fún wa.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/