Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́Àpẹrẹ

Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́

Ọjọ́ 2 nínú 3

Oore-ọ̀fẹ́; Oore-ọ̀fẹ́ mú un dúró

Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ náà "mú un dúró". Ẹ wòye nínú àká ẹ̀ṣẹ́ jíjà, níbi tí ajẹ̀ṣẹ́ kan ti ń kojú alátakò rẹ̀. Lọ́gán tí ajẹ̀ṣẹ́ náà bá ti wọ àkókò ìsinmi rẹ̀, olùtọ́jú kan yóò sáré tọ̀ ọ́ lọ láti ràn án lọ́wọ́. Olùtọ́jú yìí mú un dúró, ó ń ràn án lọ́wọ́ láti ní àṣeyọrí nínú àfojúsùn rẹ̀. Èyí farapẹ́ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ máa ń ṣe fún wa.

Oore-ọ̀fẹ́ máa ń mú gbogbo ẹ̀ka ìgbé ayé onígbàgbọ́ dúró. Oore-ọ̀fẹ́ mú ajẹ̀ṣẹ́ dúró, pèsè okun ẹ̀ṣẹ́, dènà àwọn ìdojúkọ mìíràn, ó sì ń mú ẹsẹ̀ máa rìn àti ojú fún ìríran. Oore-ọ̀fẹ́ kìí bẹ̀rẹ̀ nǹkan nìkan, ó máa ń mú un dúró pẹ̀lú. Àpẹẹrẹ yìí kò ṣe àfihàn pé a mú wa dúró nípa ipá olùtọ́jú, bí kò ṣe pé gbogbo nǹkan nínú ayé wa ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mú dúró.

Ọ̀kan lára ohun tó ń mú wa kúrò nínú ìgbésẹ̀ ni nígbà tí a bá kojú àárẹ̀ tàbí ìpéníjà. Páùlù sọ nínú ẹsẹ ìsàlẹ̀ yìí :

... Nítorí náà, láti pá mí mọ́ kúrò nínú dídi agbéraga, a fún mi ní ẹ̀gún nínú ẹran ara mi, ìránṣẹ́ láti ọ̀dọ Sátánì láti dààmú mi àti láti pa á mọ́ kúrò nínú dídi agbéraga. Mo bẹ Ọlọ́run ní ẹ̀ẹ̀mẹta láti mú un kúrò. Ìgbà kọ̀ọ̀kan Ó ní "oore-ọ̀fẹ́ mi ni gbogbo ohun tó o nílò. Agbára mi ṣiṣẹ́ dára jù nínú àárẹ̀." Nítorí náà báyìí inú mi dùn láti fọ́nnu nípa àárẹ̀ mi ki agbára Krístì lè ṣiṣẹ́ láti inú mi

Oore-ọ̀fẹ́ ni gbogbo ohun tí a nílò láti mú wa dúró nínú ìrìn àjò ayé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro, Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni ìdákòró fún ọkàn wa. Agbára rẹ̀ jẹ́ àfihàn nínú àárẹ̀ wá. Nítorí náà, kí a rí ìdùnnú nínú àárẹ̀, èébú, ìpọ́njú, ìdojúkọ àti wàhálà tí a ń kojú gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́ní.

'Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nígbà tí wàhálà kan bá dé sí ọ̀nà yín, ẹ wòó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ayọ̀ ńlá. "Nítorí tí ìwọ mọ̀ pé nígbà tí a bá dán ìgbàgbọ́ rẹ wò, ìfaradà rẹ ní àǹfààní láti dàgbà." Nítorí náà jẹ́ kí ó dàgbà, nítorí nígbà tí ìfaradà rẹ bá ti dàgbà tán, wàá di pípé, láì nílò ohunkóhun. '

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Ifarafun Oore-ọ̀fẹ́

Oore-ọ̀fẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run tí kòdá lórí ohunkóhun tí a ṣe tàbí tóṣe. ó mú wa tọ́ lojú Ọlọ́run. Nípa rẹ̀ ni a gbàwá là. Nípa rẹ̀ lafi lè béèrè ìdáríjì. Kòwà k’ẹ̀ṣẹ̀ máa pọ̀sí. Kìí ṣ’èrè ohun rere tí a ṣe, kò sẹ́ni tí ó lè fọ́nnu nípa rẹ̀. A mọ́ pé ìrìn pẹ̀lú Ọlọ́run kìí ṣe nípa ipá tàbí agbára ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí tó fún wa.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/