Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀Àpẹrẹ
Àwọn Kókó Ìgbéyàwó Márùn-ún
Láti ní òye tó jinlẹ̀ nipa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tí ó ṣètò ìbáṣepọ̀ ìyànu alálòpẹ́ láàrin ọkùnrin àti obìnrin, ìrànlọ́wọ́ ni láti yiri àwọn kókó márùn-ún wọ̀nyí wò.
Kókó àkọ́kọ́ ni Ìbáṣepọ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ti kà á ní ọjọ́ bí méjì sẹ́yìn. Àwọn nǹan ń lọ déédéé fún Adamu nínú ọgbà Edẹni, kí Eefa tó dé. Síbẹ̀ kò dára kí òun nìkan dá wà. Yálà ó mọ̀ ọ́n tàbí kò mọ̀ ọ́n, í nílò olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ̀.
Kókó kejì ti ìgbéyàwó ni ìbímọ. Ọlọ́run bùkún fún Adamu àti Eefa, ó sọ fún wọn láti bí ọmọ, tí àwọn pẹ̀lú yóò lọ bí ọmọ sí i, kí wọ́n sì gbilẹ̀ ní ayé. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí, kì í ṣe gbogbo àwọn lọ́kọláyà ló ní ọmọ, ṣùgbọ́n ìgbéyàwó àti ìdílé jẹ́ ètì rere fún ìṣẹ́dàá ọmọnìyàn.
Kókó ìgbéyàwó kẹta ni Ìjẹ́rìí. Ìgbéyàwó jẹ́ àmì alààyè ti Kristi àti ìjọ. Àlòpẹ́, ìṣọ̀kan, àti ọ̀rẹ́-tímọ́ nítorí náà ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó, bí a ṣe ń yiri ìpè náà wò, a ní láti ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu àti ìfarajìn sí ayé nípa àwọn ìgbéyàwó wa.
Kókó ìgbéyàwó kẹrin ni Ìwà Mímọ́. Ẹ̀bùn ìyanu tí í ṣe ìbálòpọ̀ ni a ṣètò láti ṣúyọ nínú ìgbéyàwó nìkan. Ìgbéyàwó ni ààyè tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìwà èérí àti ìwà ìbàjẹ́ ti ìbálòpọ̀.
Kókó karùn-ún ti ìgbéyàwó ni Ìgbádùn (èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà mímọ́). Ọ̀kan nínú ìbùkún ńláǹlà ìgbéyàwó ni àǹfààní láti gbádùn ìdàpọ̀ nípa tara lọ́nà tó láàbò tó sì ní ipò déédéé. O kò lè di mímọ̀ ju bí o ṣe wà lọ nígbà tí o bá ní ìbáṣepọ̀ lọ́kọláya pẹ̀lú ẹnìkan, ìgbéyàwó sì pèsè àyíká ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀ké fún èyí. Ìdí nìyí tí àìṣòótọ́ fi máa ń gún ni dé pinpin. Ó jẹ́ láti da ẹni tí o tin í ìdàpọ̀ tímọ́tímọ́ tí ó lágbára jùlọ pẹ̀lú.
Ìgbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn ìyànu nítorí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Aṣẹ̀dá wa ẹni tí ó pọ̀ ní oore. Gbogbo wa yẹ kí ó wá ọ̀nà láti bu ọlá fún ìgbéyàwó – bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, bí a ṣe ń lépa rẹ̀, bí a ṣe ń gbé nínú rẹ̀, àti bí a ṣe ń gba àwọn ẹni tí ń gbé nínú rẹ̀ níyànjú. A ní láti ṣe èyí nítorí pé ìgbéyàwó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Ó sì tún jẹ́ àǹfààní kan fún ìfarajìn alálòpẹ́ sí ẹnikan nínú òtítọ́ àti ìfẹ́ – àwòrá ìfẹ́ Kristi fún, àti ìfarajìn sí Ìjọ Rẹ̀. Ògo ni fún Ọlọ́run, fún ẹ̀bùn ńlá tí ó ti pèsè.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Yálà ó ti ṣègbéyàwó tàbí o fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-mkta yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ètò rere Ọlọ́run fún ìfarajìn títí-ayé fún ọkọ àti aya. Kọ́ bí a ti ń ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu fún ìyàwó Rẹ̀, ìjọ, nípa ṣíṣe àwàjinlẹ̀ àwọn kókó bí i ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ìbímọ, ìjẹ́rìí, ìjẹ́-mímọ́, àti ìgbádùn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kip' Chelashaw fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://christchurchke.org/